20 Ṣùgbọ́n tí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí iná jó jáde wá láti ọ̀dọ̀ Ábímélékì kí ó sì jó yín run. Ẹ̀yin ará Ṣékémù àti ará Bétí-Mílò, kí iná pẹ̀lú jáde láti ọ̀dọ̀ yín wá ẹ̀yin ará Ṣékémù àti ará Bétí-Mílò kí ó sì jó Ábímélékì run.”
21 Lẹ́yìn tí Jótamù ti sọ èyí tan, ó sá àṣálà lọ sí Béérì, ó sì gbé níbẹ̀ nítorí ó bẹ̀rù arákùnrin rẹ̀ Ábímélékì.
22 Lẹ́yìn tí Ábímélékì ti ṣe àkóso Ísírẹ́lì fún ọdún mẹ́ta,
23 Ọlọ́run rán ẹ̀mí búburú sáàárin Ábímélékì àti àwọn ará Ṣékémù, àwọn ẹni tí ó hu ìwà ọ̀tẹ̀.
24 Ọlọ́run ṣe èyí láti gbẹ̀san àwọn ìwà búburú, àti ìtàjẹ̀ sílẹ̀ àwọn àádọ́rin (70) ọmọ Jérúbù-Báálì lára Ábímélékì arákùnrin wọn àti lára àwọn ènìyàn Ṣékémù, ẹni tí ó ràn án lọ́wọ́ láti pa àwọn arákùnrin rẹ̀.
25 Nítorí ìkórira tí wọ́n ni sí àwọn olórí, ni Ṣékémù dẹ àwọn ènìyàn sí àwọn orí òkè láti máa dá àwọn ènìyàn tó ń kọja lọ́nà, kí wọn sì máa jà wọ́n lólè, àwọn kan ló sọ èyí fún Ábímélékì.
26 Gáálì ọmọ Ébédì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ wá sí Ṣékémù, àwọn ará Ṣékémù sì gbàgbọ́ wọ́n sì fi inú tán wọn.