26 Gáálì ọmọ Ébédì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ wá sí Ṣékémù, àwọn ará Ṣékémù sì gbàgbọ́ wọ́n sì fi inú tán wọn.
27 Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jáde lọ sí oko, wọ́n sì ṣa èṣo àjàrà wọn jọ, wọ́n fún èṣo àjàrà náà, wọ́n si ṣe àjọ̀dún nínú ilé òrìṣà wọn. Nígbà tí wọ́n ń jẹ tí wọ́n ń mu wọ́n fi Ábímélékì ré.
28 Gáálì ọmọ Ébédì dáhùn pé, “Ta ni Ábímélékì tàbí tani Ṣékémù tí àwa ó fi sìn ín? Ọmọ Jerubu-Báálì kọ́ ní ṣe tàbí Ṣébútì kọ́ ní igbá kejì rẹ̀? Ẹ má sin àwọn ará Hámórì baba àwọn ará Ṣékémù, Èéṣe tí a ó fi sin Ábímélékì?
29 Bí àwọn ènìyàn yìí bá wà ní abẹ́ ìsàkóso mi ni! Ẹ̀yin ó bọ́ àjàgà rẹ̀ kúrò ní ọrùn yín (Èmi yóò yọ Ábímélékì kúrò). Èmi ó ò wí fún Ábímélékì pé, ‘Kó gbogbo àwọn ogun rẹ jáde láti jà.’ ”
30 Nígbà tí Ṣébúlù, alákoṣo ìlú náà gbọ́ ohun tí Gáálì ọmọ Ébédì sọ, inú bí i gidigidi.
31 Ó ránṣẹ́ sí Ábímélékì pé, “Gáálì ọmọ Ébédì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ wá láti máa gbé ní Ṣékémù ṣùgbọ́n, wọ́n ń rú àwọn ènìyàn sókè láti sọ̀tẹ̀ sí ọ.
32 Wá ní òru kí ìwọ àti àwọn ogun rẹ sá pamọ́ dè wọ́n nínú igbó.