4 Wọ́n fún un ní àádọ́rin ṣékélì fàdákà láti ilé òrìṣà Bááli-Béritì, Ábímélékì fi owó náà gba àwọn jàǹdùkú àti aláìníláárí ènìyàn tí wọ́n sì di olùtẹ̀lé rẹ̀.
5 Ó kó wọn lọ sí ilé baba rẹ̀ ní Ófírà, níbẹ̀ ní orí òkúta kan ṣoṣo ni ó ti pa àádọ́rin nínú àwọn arákùnrin rẹ̀, àwọn Jérú-Báálì, ṣùgbọ́n Jótamù, àbíkẹ́yìn nínú àwọn ọmọ Jérúb-Báálì, bọ́ yọ nítorí pé ó sá pamọ́.
6 Gbogbo àwọn ará Ṣékémù àti àwọn ará Bẹti-Mílò pàdé pọ̀ ní ẹ̀bá igi óákù ní ibi òpó ní Ṣékémù láti fi Ábímélékì jọba.
7 Nígbà tí wọ́n sọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ yìí fún Jótamù, ó gun orí ṣóńṣó òkè Gérísímì lọ, ó sì ké lóhùn rara pé, “Ẹ tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin àgbààgbà Ṣékémù, kí Olúwa le tẹ́tí sí yín.
8 Ní ọjọ́ kan àwọn igi jáde lọ láti yan ọba fún ara wọn. Wọ́n pe igi Ólífì pé, ‘Wá ṣe ọba wa.’ ”
9 “Ṣùgbọ́n igi Ólífì dá wọn lóhùn pé, ‘Èmi yóò ha fi òróró mi sílẹ̀ èyí tí a ń lò láti fi ọ̀wọ̀ fún àwọn ọlọ́run àti ènìyàn kí èmi sì wá ṣolórí àwọn igi?’
10 “Àwọn igi sọ fún igi ọ̀pọ̀tọ́ pé, ‘Wá jọba ní orí wa.’