1 A sì fi ìféèfé kan fún mi tí o dàbí ọ̀pá: ẹnìkan sì wí pé, “Dìde, wọn tẹ́ḿpílì Ọlọ́run, àti pẹpẹ, àti àwọn tí ń sìn nínú rẹ̀.
2 Sì fi àgbàlá tí ń bẹ lóde tẹ́ḿpìlì sílẹ̀, má si ṣe wọ̀n ọ́n; nítorí tí a fi fún àwọn aláìkọlà: ìlú mímọ́ náà ni wọn ó sì tẹ̀ mọ́lẹ̀ ní oṣù méjì lé lógójì.
3 Èmi ó sì yọ̀ǹda fún àwọn ẹlẹ̀rìí mi méjèèje, wọn o sì sọtẹ́lẹ̀ fún ẹgbẹ̀fa ọjọ́ ó-lé-ọgọ́ta nínú aṣọ-ọ̀fọ̀.”
4 Wọ̀nyí ni igi olífì méjì náà, àti ọ̀pá fìtílà méjì náà tí ń dúró níwájú Olúwa ayé.
5 Bí ẹnikẹ́ni bá sì fẹ́ pa wọn lara, iná ó ti ẹnu wọn jáde, a sì pa àwọn ọ̀ta wọn run: bayìí ni a ó sì pa ẹnikẹ́ni tí ó ba ń fẹ́ pa wọn lára run.
6 Àwọn wọ̀nyí ni ó ni agbára láti sé ọ̀run, tí òjò kò fi lè rọ̀ ni ọjọ́ àsọtẹ́lẹ̀ wọn: wọ́n sì ní agbára lórí omi láti sọ wọn di ẹ̀jẹ̀, àti láti fi onírúurú àjàkálẹ̀-àrùn kọlu ayé, nígbàkúgbà tí wọ́n bá fẹ́.