Ìfihàn 4 BMY

Ìtẹ́ Ọ̀run

1 Lẹ́yin nǹkan wọ̀nyí èmi wò, sì kíyèsí i, ìlẹ̀kùn kan ṣí sílẹ̀ ní ọ̀run: Ohùn kìn-ín-ní tí mo gbọ́ bí ohùn ìpè tí ń bá mi sọ̀rọ̀, tí ó wí pé, “Gòkè wá níhìn-ín, èmi ó sì fi ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ̀yìn èyí hàn ọ́.”

2 Lójú kan náà, mo sì wà nínú Ẹ̀mí: sì kíyèsí i, a tẹ́ ìtẹ́ kan lọ́run ẹnìkan sì jókòó lórí ìtẹ́ náà.

3 Ẹni tí ó sì jókòó náà dàbí òkúta jásípérì àti sádíúsì lójú. Ni àyíká ìtẹ́ náà ni òṣùmàrè kan wà tí ó dàbí òkúta émérádì lójú.

4 Yíká ìtẹ́ náà sì ni ìtẹ́ mẹ́rínlélógún; àti lórí àwọn ìtẹ́ náà mo rí àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún jókòó, tí a wọ̀ ni aṣọ àlà; adé wúrà sì wà ni orí wọn.

5 Àti láti ibi ìtẹ́ náà ni ìró mọ̀nàmọ́ná àti ohùn àti àrá ti jáde wá: níwájú ìtẹ́ náà ni fìtílà iná méje sì ń tàn, èyí tí ń ṣe Ẹ̀mí méje ti Ọlọ́run.

6 Àti láti ibi ìtẹ́ náà ni òkun bi digi wà tí o dàbí Kírísítálì: Àti yí ìtẹ́ náà ká ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan ni ẹ̀dá alààyè mẹ́rin tí ó kún fún ojú níwájú àti lẹ̀yìn wà.

7 Ẹ̀dá kínní sì dàbí kìnnìún, ẹ̀dá kéjì si dàbí ọmọ màlúù, ẹ̀dá kẹta sì ni ojú bi ti ènìyàn, ẹ̀dá kẹ́rin sì dàbí ìdì tí ń fò.

8 Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, tí olúkúlùkù wọn ni ìyẹ́ mẹ́fà, kún fún ojú yíká ara àti nínú; wọn kò sì sinmi lọ́sàn-ań àti lóru, láti wí pé:“Mímọ́, Mímọ́, Mímọ́,Olúwa Ọlọ́run Olódùmare,tí ó ti wà, tí ó sì ń bẹ, tí ó sì ń bọ̀ wá!”

9 Nígbà tí àwọn ẹ̀dá aláàyè náà bá sì fi ògo àti ọlá, àti ọpẹ́ fún ẹni tí o jókòó lórí ìtẹ́, tí o ń bẹ láàyè láé àti láéláé.

10 Àwọn àgbà mẹ́rinlélógún náà yóò sì wólẹ̀ níwájú ẹni tí o jókòó lórí ìtẹ́, wọn yóò sì tẹríba fún ẹni tí ń bẹ láàyè láé àti láéláé, wọn yóò sì fi adé wọn lélẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà, wí pé:

11 “Olúwa, ìwọ ni o yẹláti gba ògo àti ọlá àti agbára:nítorí pé ìwọ ni o dá ohun gbogbo,àti nítorí ìfẹ́ inú rẹ̀ niwọn fi wà tí a sì dá wọn.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22