Ìfihàn 17 BMY

Obìnrin Àti Ẹranko

1 Ọ̀kan nínú àwọn ańgẹ́lì méje náà tí ó ní ìgò méje wọ̀n-ọn-nì sì wá, ó sì ba mi sọ̀rọ̀ wí pé, “Wá níhìn-ín; èmi ó sì fi ìdájọ́ àgbèrè ńlá ní tí ó jókòó lórí omi púpọ̀ han ọ:

2 Ẹni tí àwọn ọba ayé bá ṣe àgbèrè, tí a sì fi ọtí wáìnì àgbèrè rẹ̀ pá àwọn tí ń gbé inú ayé.”

3 Ó sì gbé mi nínú ẹ̀mí lọ sí ihà: mo sì rí obìnrin kan ó jòkòó lórí ẹranko aláwọ̀ òdòdó kan tí ó kún fún orúkọ ọ̀rọ̀ òdì, ó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá.

4 A sì fi aṣọ elése àlùkò àti aṣọ odòdó wọ obìnrin náà, a sì fi wúrà àti òkúta iyebíye àti pérílì ṣe é lọ́sọ̀ọ́, ó ní ago wúrà kan ní ọwọ́ rẹ̀, tí ó kún fún ìríra àti fún ẹ̀gbin àgbérè rẹ̀;

5 Àti níwájú rẹ̀ ni orúkọ kan tí a kọ:OHUN ÌJÌNLẸ̀BÁBÍLÓNÌ ŃLÁÌYÁ ÀWỌN PANṢÁGÀÀTI ÀWỌN OHUN ÌRÍRA AYÉ.

6 Mo sì rí obìnrin náà mu ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́, àti ẹ̀jẹ̀ àwọn ajẹ́rìí ikú Jésù ní àmuyó.Nígbà tí mo sì rí i, ẹnu yà mi gidigidi.

7 Ańgẹ́lì sì wí fún mi pé, “Nítorí kí ni ẹnu ṣe yà ọ́? Èmi ó sọ ti ìjìnlẹ̀ obìnrin náà fún ọ, àti ti ẹranko tí ó gùn, ti ó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá.

8 Ẹranko tí ìwọ ri nì, o ti wà, kò sì sí mọ́: Yóò sì ti inú ọ̀gbun gòkè wá, yóò sì lọ sínú ìwé iye láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, nígbà tí wọn ń wò ẹranko tí o ti wà, tí kò sì sí mọ́, tí ó sì ń bọ̀ wá.

9 “Níhìn-ín ni ìtumọ̀ tí o ní ọgbọ́n wà. Orí méje ni òkè ńlá méje ni, lórí èyí tí obìnrin náà jókòó.

10 Ọba méje sì ní wọn: àwọn márùn-ún ṣubú, ọ̀kan ń bẹ, ọ̀kan ìyókù kò sì tí ì dé; nígbà tí ó bá sì dé, yóò dúró fún ìgbà kúkurú.

11 Ẹranko tí ó sì ti wà, tí kò sì sí, òun náà sì ni ìkẹjọ, ó sì ti inú àwọn méje náà wá, ó sì lọ sí ìparun.

12 “Ìwo mẹ́wáà tí ìwọ sì rí ni ọba mẹ́wàá ni wọn, tí wọn kò ì ti gba ìjọba; ṣùgbọ́n wọn gba ọlá bí ọba pẹ̀lú ẹranko náà fún wákàtí kan.

13 Àwọn wọ̀nyí ní inú kan, wọ́n ò sì fi agbára àti ọlá wọn fún ẹranko náà.

14 Àwọn wọ̀nyí ni yóò si máa bá Ọ̀dọ́ Àgùntàn jagun, Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà yóò sì ṣẹ́gun wọn: nítorí òun ni Olúwa àwọn Olúwa, àti Ọba àwọn ọba: Àwọn tí ó sì wà pẹ̀lú rẹ̀, tí a pè, tí a yàn, tí wọ́n sì jẹ́ olóòtọ́ yóò sì sẹ́gun pẹ̀lú.”

15 Ó sì wí fún mi pé, “Àwọn omi tí ìwọ ti rí ni, níbi tí àgbèrè náà jókòó, àwọn ènìyàn àti ẹ̀yà àti orílẹ̀ àti oníruru èdè ni wọ́n.

16 Àti ìwo mẹ́wàá tí ìwọ rí, àti ẹranko náà, àwọn wọ̀nyí ni yóò koríra àgbèrè náà, wọn ó sì sọ ọ́ di ahoro àti ẹni ìhòòhò, wọn ó sì jẹ ẹran ara rẹ̀, wọn ó sì fi iná sun ún pátapáta.

17 Nítorí Ọlọ́run ti fi sínú ọkàn wọn láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ, láti ní inú kan, àti láti fi ìjọba wọn fún ẹranko náà, títí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yóò fi ṣẹ

18 Obìnrin tí ìwọ rí ní ìlú ńlá ni, tí ń jọba lórí àwọn ọba ilẹ̀ ayé.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22