Ìfihàn 10 BMY

Àwọn Ańgẹ́lì Àti Ìwé Kékeré

1 Mó sì rí ańgẹ́lì mìíràn alágbára ò ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, a fi awọsànmà wọ̀ ọ́ ni aṣọ; òṣùmàrè sì ń bẹ ní orí rẹ̀, ojú rẹ̀ sì dàbí òòrùn, àti ẹṣẹ̀ rẹ̀ bí ọ̀wọ́n iná.

2 Ó sì ní ìwé kékeré kan tí a sí ní owọ́ rẹ̀; ó sì fi ẹṣẹ rẹ̀ ọ̀tún lé òkun, àti ẹṣẹ̀ rẹ̀ òsì lé ilẹ̀.

3 Ó sì ké lóhùn rara, bí ìgbà tí kìnnìún bá bú ramúramù. Nígbà tí ó sì ké, àwọn àrá méje náà fọhùn.

4 Nígbà tí àwọn àrá méje fọhùn, mo múra àti kọ̀wé: mo sì gbọ ohùn láti ọ̀run wá ń wí fún pé, “Fi èdìdì di ohun tí àwọn àrá méje náà sọ, má sì ṣe kọ wọ́n sílẹ̀.”

5 Ańgẹ́lì náà tí mo rí tí ó dúró lórí òkun àti lórí ilẹ̀, sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sí òkè ọ̀run:

6 Ó sì fi ẹni tí ń bẹ láàyè láé àti láé láé búra, ẹni tí o dá ọ̀run, àti ohun tí ń bẹ nínú rẹ̀, pé, “Kí a má ṣe jáfara mọ́.

7 Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ ohùn ìpè ańgẹ́lì kéje, nígbà tí yóò ba fún ìpè, nígbà náà ni ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí o tí sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn wòlíì ni a ó mú ṣẹ.”

8 Ohùn náà tí mo gbọ́ láti ọ̀run tún ń ba mi sọ̀rọ̀, ó sì wí pé, “Lọ, gba ìwé tí a ṣí náà lọ́wọ́ ańgẹ́lì tí o dúró lórí òkun àti lórí ilẹ̀.”

9 Mo sì tọ ańgẹ́lì náà lọ, mo sì wí fún pé, “Fún mi ní ìwé kékeré náà.? Ó sì wí fún mi pé, ‘Gbà kí o sì jẹ ẹ́ tan: yóò dàbí oyin.’ ”

10 Mo sì gba ìwé kékeré náà ni ọwọ́ ańgẹ́lì náà mo sì jẹ ẹ́ tan; ó sì dùn lẹ́nù mi bí oyin; bí mo sì tí jẹ ẹ́ tan, inú mi korò.

11 A sì wí fún mi pé, “Ìwọ ó sì tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn, àti orílẹ̀ àti èdè, àti àwọn ọba.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22