Ìfihàn 21 BMY

Jerúsálémù Tuntun

1 Mo sì rí ọ̀run titun kan àti ayé titun kan: nítorí pé ọ̀run ti ìṣáajú àti ayé ìṣáajú ti kọjá lọ; òkun kò sì sí mọ́.

2 Mo sì rí ìlú mímọ́, Jerúsálémù titun ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, tí a ti múra sílẹ̀ bí ìyàwó tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ fún ọkọ rẹ̀.

3 Mo sì gbọ́ ohùn ńlá kan láti orí ìtẹ́ náà wá, ń wí pé, “Kíyèsi i, àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú àwọn ènìyàn, òun ó sì máa bá wọn gbé, wọn ó sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀, àti Ọlọ́run tìkararẹ̀ yóò wà pẹ̀lú wọn, yóò sì máa jẹ́ Ọlọ́run wọn.

4 Ọlọ́run yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ni ojú wọn; kì yóò sì sí ikú mọ́, tàbí ọ̀fọ̀, tàbí ẹkún, bẹ́ẹ̀ ni kí yóò sí ìrora mọ́: nítorí pé ohun àtijọ́ tí kọjá lọ.”

5 Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà, sì wí pé, “Kíyèsi i, mo sọ ohun gbogbo di ọ̀tun!” Ó sì wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀: Nítorí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí òdodo àti òtítọ́ ni wọ́n.”

6 Ó sì wí fún mi pé, “Ó parí. Èmi ni Álfà àti Ómégà, ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti òpin. Èmi ó sì fi omi fún ẹni tí oúngbẹ ń gbẹ láti orísun omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.

7 Ẹni tí ó ba ṣẹ́gun ni yóò jogún nǹkan wọ̀nyí; èmi ó sì máa jẹ́ Ọlọ́run rẹ̀, òun ó sì máa jẹ ọmọ mi.

8 Ṣùgbọ́n àwọn ojo, àti aláìgbàgbọ́, àti ẹni ìríra, àti apànìyàn, àti àgbèrè, àti oṣó, àti abọ̀rìṣà, àti àwọn èké gbogbo, ni yóò ni ipa tiwọn nínú adágún tí ń fí iná àti súfúrù jó: èyí tí i ṣe ikú kéjì.”

9 Ọ̀kan nínú àwọn ańgẹ́lì méje, tí wọ́n ni ìgò méje, tí ó kún fún ìyọnu méje ìkẹyìn sì wá, ó sì ba mi sọ̀rọ̀ wí pé, “Wá níhìnín, èmi ó fi ìyàwó, aya Ọ̀dọ́-Àgùntàn hàn ọ́.”

10 Ó sì mu mi lọ nínú Ẹ̀mí si òkè ńlá kan tí o sì ga, ó sì fí ìlú náà hàn mi, Jerúsálémù mímọ́, tí ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run,

11 Tí ó ní ògo Ọlọ́run: ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ sì dàbí òkúta iyebíye gidigidi, àní bí òkúta Jasípérì, ó mọ́ bí Kírísítálì;

12 Ó sì ní odi ńlá àti gíga, ó sì ni ẹnu-bodè méjìlá, àti ní àwọn ẹnu-bodè náà áńgẹ́lì méjìlá àti orúkọ tí a kọ sára wọn tí i ṣe orúkọ àwọn ẹ̀yà méjìlá tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì;

13 Ní ìhá ìlà-oòrùn ẹnu-bodè mẹ́ta; ní ìhà àríwá ẹnu-bodè mẹ́ta; ní ìhà gúsù ẹnu-bodè mẹ́ta; àti ní ìhà ìwọ̀-òòrùn ẹnu-bodè mẹ́ta.

14 Odi ìlú náà sì ni ìpìlẹ̀ méjìlá, àti lórí wọn orúkọ àwọn Àpósítélì méjìlá tí Ọ̀dọ́-Àgùntàn.

15 Ẹni tí o sì ń bá mi sọ̀rọ̀ ní ọ̀pá-ìwọ̀n wúrà kan láti fi wọn ìlú náà àti àwọn ẹnu-bodè rẹ̀, àti odi rẹ̀.

16 Ìlú náà sì wà ní ibú mẹ́rin lọ́gbọọgba, gígùn rẹ̀ àti ìbú rẹ̀ sì dọ́gba: ó sì fi ọ̀pá-ìwọ̀n náà wọn ìlú náà wò, ó jẹ ẹgbàafà ibùsọ̀ gígùn rẹ̀ àti ìbú rẹ̀, àti gíga rẹ̀ sì dọ́gba.

17 Ó sì wọn odi rẹ̀ ó jẹ̀ ogóje ìgbọ̀nwọ́ lé mẹ́rin (144), gẹ́gẹ́ bí òṣùwọ̀n ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni tí ańgẹ́lì náà.

18 A sì fi Jásípérì mọ odi ìlú náà. Ìlú náà sì jẹ́ kìkì wúrà, ó dàbí dígí tí o mọ́ kedere.

19 A fi onírúuru òkúta iyebíye ṣe ìpìlẹ̀ ògiri ìlú náà lọ́ṣọ̀ọ́. Ìpìlẹ̀ ìkínní jẹ́ jásípérì; ìkejì, sáfírù; ìkẹta, kalíkedónì ìkẹrin, emeralídì.

20 Ikarun, sadonikísì; ìkẹfà, kanelíánì; ìkeje, kírisolítì; ìkẹjọ bérílì; ìkẹsan, tọ́pásì; ìkẹwàá, kírísopírasù; ìkọkànlá, jakinítì; ìkejìlá, ámétísítì.

21 Ẹnu-bodè méjèèjìlá jẹ́ pẹ́rílì méjìlá: olúkúlùkù ẹnu-bodè jẹ́ pérílì kan; ọ̀nà ìgboro ìlú náà sì jẹ́ kìkì wúrà, ó dàbí dígí dídán.

22 Èmi kò sì ri tẹḿpílì nínú rẹ̀: nítorí pé Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè ni téḿpílì rẹ̀, àti Ọ̀dọ́-Àgùntàn.

23 Ìlú náà kò sì ní oòrùn, tàbí òṣùpá, láti máa tan ìmọ́lẹ̀ sí i: nítorí pé ògo Ọlọ́run ni ó ń tàn ìmọ́lẹ̀ sí i, Ọ̀dọ́-Àgùntàn sì ni fìtílà rẹ̀.

24 Àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì máa rìn nípa ìmọ́lẹ̀ rẹ̀: àwọn ọba ayé sì ń mú ògo wọn wá sínú rẹ̀.

25 A kì yóò sì ṣé àwọn ẹnu-bodè rẹ̀ rárá ní ọ̀sán: nítorí ki yóò si òru níbẹ̀.

26 Wọ́n ó sì máa mú ògo àti ọlá àwọn orílẹ̀-èdè wá sínú rẹ̀.

27 Ohun aláìmọ́ kan ki yóò sì wọ inú rẹ̀ rárá, tàbí ohun tí ń ṣiṣẹ́ ìríra àti èké; bí kò ṣe àwọn tí a kọ sínú ìwé ìyè Ọ̀dọ́-Àgùntàn.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22