Ìfihàn 14 BMY

Ọ̀dọ́-Àgùntàn Àti Oke Méje-ó-lé egbàá-méjì

1 Mo sì wo, si kíyèsí i, Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà dúró lórí Òkè Síónì, àti pẹ̀lú rẹ̀ ọ̀kẹ́ méje-ó-lé ẹgbàájì ènìyàn; wọ́n ní orúkọ rẹ̀, àti orúkọ baba rẹ̀ tí a kọ sí iwájú-orí wọn.

2 Mo sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run wá, bí aríwo omi púpọ̀, àti bí sísán àrá ńlá: mo sì gbọ́ àwọn oníháàpù, ń lù haàpù wọn.

3 Wọ́n sì ń kọ bí ẹni pé orin túntún níwájú ìtẹ́ náà, àti àwọn àgbà náà: kò sì sí ẹni tí o lè kọ orin náà, bí kò ṣe àwọn òkè méje o lé ẹgbàájì ènìyàn, tí a tí rà padà láti inú ayé wá.

4 Àwọn wọ̀nyí ni a kò fi obìnrin sọ di èérì: nítorí tí wọ́n jẹ́ wúndíá. Àwọn wọ̀nyí ni o ń tọ Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà lẹ́yìn níbikíbi tí o bá ń lọ. Àwọn wọ̀nyí ni a ràpadà láti inú àwọn ènìyàn wá, wọ́n jẹ́ àkọ́so fún Ọlọ́run àti fún Ọ̀dọ̀-Àgùntàn náà.

5 A kò sì rí èké lẹ́nu wọn, wọn jẹ́ aláìlábùkù.

Àwọn Ańgẹ́lì Mẹ́ta

6 Mo sì rí ańgẹ́lì mìíràn ń fò ní àárin méjì ọ̀run, pẹ̀lú Ìyìn rere àìnípẹ̀kun láti wàásù fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé, àti fún gbogbo orílẹ̀, àti ẹ̀yà, àti èdè, àti ènìyàn.

7 Ó ń wí ni ohùn rara pé, “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ogo fún un, nítorí tí wákàtí ìdájọ́ rẹ̀ dé: ẹ sì foríbàlẹ́ fún ẹni tí o dá ọ̀run, àti ayé, àti òkun, àti àwọn orísun omi!”

8 Ańgẹ́lì mìíràn sì tẹ̀lé e, ó ń wí pé, “Ó ṣubú, Bábílónì ńlá ṣubú, èyí ti o tí ń mú gbogbo orílẹ̀-èdè mu nínú ọtí wáìnì àìmọ́ àgbèrè rẹ̀!”

9 Ańgẹ́lì mìíràn, ẹ̀kẹta, sì tẹ̀lé wọn, ó ń wí ni ohùn rara pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá ń fóríbalẹ̀ fún ẹranko náà àti àwòrán rẹ̀, tí ó sì gba àmì sí iwájú orí rẹ̀ tàbí sí ọwọ́ rẹ̀.

10 Òun pẹ̀lú yóò mú nínú ọtí-wáìnì ìbínú Ọlọ́run, tí a dà láìní àbùlà sínú ago ìrúnnú rẹ̀; a ó sì fi iná sufúrù dá a lóró níwájú àwọn ańgẹ́lì mímọ́, àti níwájú Ọ̀dọ́-Àgùntàn:

11 Èéfín ìdálóró wọn ń lọ sókè títí láéláé wọn kò sì ní ìsinmi ni ọ̀sán àti ní òru, àwọn tí ń foríbalẹ̀ fún ẹranko náà àti fún àwòrán rẹ̀, àti ẹnikẹ́ni tí o ba sì gba àmì orúkọ rẹ̀.”

12 Nihìn-ín ni sùúrù àwọn ènìyàn mímọ́ gbé wà: àwọn tí ń pa òfin Ọlọ́run àti ìgbàgbọ́ Jésù mọ́.

13 Mo sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run wá ń wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀: Alábùkún fún ni àwọn òkú tí o kú nínú Olúwa láti ìhín lọ.”Alábùkún ni wọ́n nítòótọ́, bẹ́ẹ̀ ni, Ẹ̀mí wí, “Nítorí tí wọn yóò sìnmí kúrò nínú làálàá wọn, nítorí iṣẹ́ wọn ń tọ̀ wọn lẹ́yìn.”

Ìkórè Ayé

14 Mo sì wo, sì kíyèsi i, ìkúùkùu àwọsánmà funfun kan, àti lóri ìkúùkùu àwọ̀sánmà náà ẹnikan jókòó tí o “dàbí Ọmọ ènìyàn,” tí òun ti adé wúrà ní orí rẹ̀, àti dòjé mímú ni ọwọ́ rẹ̀.

15 Ańgẹ́lì mìíràn sì tí inú tẹḿpìlì jáde wa tí ń ké lóhùn rara sí ẹni tí ó jókòó lórí ìkúùkùu àwọsánmà náà pé, “Tẹ dòjé rẹ bọ̀ ọ́, kí ó sì máa kórè; nítorí àkókò àti kórè dé, nítorí ìkórè ayé ti gbó tán.”

16 Ẹni tí ó jókòó lórí ìkúùkùu àwọsánmà náà sì tẹ dòjé rẹ̀ bọ orí ilẹ̀ ayé; a sì ṣe ìkórè ilẹ̀ ayé.

17 Ańgẹ́lì mìíràn sì tí inú tẹmpílì tí ń bẹ ni ọ̀run jáde wá, òun pẹ̀lú sì ní dòjé mímú, kan.

18 Ańgẹ́lì mìíràn sì tí ibi pẹpẹ jáde wá, tí ó ní agbára lórí iná; ó sì ké ni ohùn rara sí ẹni tí o ni dòjé mímú náà, wí pé, “Tẹ dòjé rẹ mímú bọ̀ ọ́, ki ó sì rẹ̀ àwọn ìdí àjàrà ayé, nítorí àwọn èso rẹ̀ tí pọ́n.”

19 Ańgẹ́lì náà sì tẹ dòjé rẹ̀ bọ ilẹ́ ayé, ó sì gé àjàrà ilẹ́-ayé, ó sì kó o lọ sínú ìfúntì, ìfúntí ńlá ìbínú Ọlọ́run.

20 A sì tẹ ìfúntí náà lẹ́yìn òde ilú náà, ẹ̀jẹ̀ sì ti inú ìfúntí náà jáde, ó sì ga sókè dé okùn ìjánu ẹṣin, èyí tí ìnàsílẹ̀ rẹ to ẹ̀gbẹjọ̀ ibùsọ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22