1 Ańgẹ́lì karùn-ún sì fún ìpè tirẹ̀ mo sì rí ìràwọ̀ kan bọ́ sílẹ̀ láti ọ̀run wá: a sì fi kọ́kọ́rọ́ ihò ọ̀gbun fún un.
2 Ó sì sí ihò ọ̀gbun náà, èéfín sì rú jáde láti inú ihò náà wá, bí èèfín ìléru ńlá, òòrùn àti ojú sánmà sì ṣóòkùn nítorí èéfín ihò náà.
3 Àwọn eṣú sì jáde ti inú èéfín náà wá sórí ilẹ̀: a sì fi agbára fún wọn gẹ́gẹ́ bí agbára àkéekèe ilẹ̀.
4 A sì fún wọn pé ki wọn má ṣe pa koríko ilẹ̀ lára tàbí ohun tútù kan, tàbí igikígi kan; bí kò ṣe àwọn ènìyàn tí kò ni èdìdì Ọlọ́run ní iwájú wọn.
5 A sì pàṣẹ fún wọn pé, kí wọn má ṣe pa wọ́n, ṣùgbọ́n kí a dá wọn ni oró ni oṣù marùn-ún: oró wọn sì dàbí oró àkéekèe, nígbà tí o bá ta ènìyàn.
6 Ní ọjọ́ wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn yóò sì máa wá ikú, wọn kì yóò sì rí i; wọn yóò sì fẹ́ láti kú, ikú yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ wọn.
7 Ìrísí àwọn eṣú náà sì dàbí àwọn ẹṣin tí a múra sílẹ̀ fún ogun; àti ní orí wọn ni ohun tí o dàbí àwọn adé wúrà wà, ojú wọn sì dàbí ojú ènìyàn;
8 Wọn sì ní irun bí obìnrin, ehín wọn sì dàbí ti kìnìún.
9 Wọn sì ní ìgbàyà tí ó dàbí ìgbàyà irin; ìró ìyẹ́ wọn sì dàbí ìró kẹ̀kẹ́ ẹsin púpọ̀ tí ń súré lọ sí ogun.
10 Wọ́n sì ni ìrù àti oró bí tí àkéekèe, àti ní ìrù wọn ni agbára wọn wà láti pa ènìyàn lára fún oṣù márùn-ún.
11 Wọ́n ní ańgẹ́lì ọ̀gbun náà bí ọba lórí wọn, orúkọ rẹ̀ ní èdè Hébérù ní Ábádónì, àti ni èdè Gíríkì orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Àpólíónì.
12 Ègbé kan tí kọjá, kíyèsi i, ègbé méjì ń bọ̀ síbẹ̀ lẹ́yìn èyí.
13 Ańgẹ́lì kẹ́fà si fún, mo sì gbọ́ ohùn kan láti ibi ìwo mẹ́rin pẹpẹ wúrà wá, tí ń bẹ níwájú Ọlọ́run.
14 Òun wí fún ańgẹ́lì kẹ́fà náà tí o ni ìpè náà pé, “Tú àwọn ańgẹ́lì mẹ́rin náà sílẹ̀ tí a dè lẹ́bàá odò ńlá Yúfúrátè!”
15 A sì tú àwọn ańgẹ́lì mẹ́rin náà sílẹ̀, tí a ti pèṣè tẹ́lẹ̀ fún wákàtí náà, àti ọjọ́ náà, àtí oṣù náà, àti ọdún náà, láti pa ìdámẹ̀ta ènìyàn.
16 Iye ogún àwọn ẹlẹ́ṣin sì jẹ́ àádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà igba: mo sì gbọ́ iye wọn.
17 Báyìí ni mo sì rí àwọn ẹṣin náà ní ojúran, àti àwọn tí o gùn wọ́n, wọ́n ni ìgbàyà aláwọ̀ iná, àti ti jàkìntì, àti tí súfúrù: orí àwọn ẹṣin náà sì dàbí orí àwọn kìninún; àti láti ẹnu wọn ni iná, àti èéfín, àti súfúrù tí ń jáde.
18 Nípa ìyọnu mẹ́ta wọ̀nyí ni a tí pa ìdámẹ̀ta ènìyàn, nípa iná, àti nípa èéfín, àti nípa súfúrù tí o ń tí ẹnu wọn jáde.
19 Nítorí pé agbára àwọn ẹṣin náà ń bẹ ní ẹnu wọn àti ní ìrù wọn: Nítorí pé ìrù wọn dàbí ejò, wọn sì ní orí, àwọn wọ̀nyí ni wọn sì fi ń pani lára.
20 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ìyókù tí a kò sì ti ipa ìyọnu wọ̀nyí pa, kò sì ronúpìwàdà iṣẹ́ ọwọ́ wọn, kí wọn má ṣe fàdákà, àti ti idẹ, àti òkúta, àti ti igi mọ́: àwọn tí kò lè ríran, tàbí kí wọn gbọ́ràn, tàbí kí wọn rìn:
21 Bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ronúpìwàdà ìwà ìpànìyàn wọn, tàbí oṣó wọn tàbí àgbérè wọn, tàbí olè wọn.