1 Àmì ńlá kan sì hàn ni ọ̀run; obìnrin kan tí a fi òòrùn wọ̀ ní aṣọ, òṣùpá sì ń bẹ lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, adé oníràwọ̀ méjìlá sì ń bẹ lórí rẹ̀:
2 Ó sì lóyún, ó sì kígbe ni ìrọbí, ó sì wà ni ìrora àti bímọ.
3 Àmì mìíràn sì hàn lọ́run; sì kíyèsí i, dírágónì pupa ńlá kan, tí ó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá, àti adé méje ní orí rẹ̀.
4 Ìrù rẹ̀ sì wọ́ ìdá mẹ́ta àwọn ìràwọ̀, ó sì jù wọ́n sí ilẹ̀ ayé, dírágónì náà sì dúró níwájú obìnrin náà tí ó fẹ́ bímọ, pé nígbà tí o bá bí i, kí òun lè pa ọmọ rẹ̀ jẹ.
5 Ó sì bi ọmọkùnrin kan tí yóò fi ọ̀pá irin ṣe àkóso gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè: a sì gba ọmọ rẹ̀ lọ sókè sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, àti sí orí ìtẹ́ rẹ̀.
6 Obìnrin náà sì sá lọ sí ihà, níbi tí a gbé ti pèṣè ààyè sílẹ̀ dè é láti ọwọ́ Ọlọ́run wá, pé kí wọ́n máa bọ́ ọ níbẹ̀ ní ẹgbẹ̀fà ọjọ́ ó-lé-ọgọ́ta.
7 Ogun sì ń bẹ ní ọ̀run: Mákẹ́lì àti àwọn ańgẹ́lì rẹ̀ bá dírágónì náà jagun; dírágónì sì jagun àti àwọn angẹ́lì rẹ̀.
8 Wọ́n kò sì lè ṣẹ́gun; Bẹ́ẹ̀ ni a kò sì rí ipò wọn mọ́ ni ọ̀run.
9 A sì lé dírágónì ńlá náà jáde, ejò láéláé ni, tí a ń pè ni Èṣù, àti Sàtanì, tí ń tan gbogbo ayé jẹ: a sì lé e jù sí ilẹ̀ ayé, a sì lé àwọn ańgẹ́lì rẹ̀ jáde pẹ̀lú rẹ̀.
10 Mo sì gbọ́ ohùn rara ní ọ̀run, wí pè:“Nígbà yìí ni ìgbàlà dé, àti agbára, àti ìjọba Ọlọ́run wá,àti ọlá àti Kírísítì rẹ̀.Nítorí a tí le olùfisùn àwọn arakùnrin wa jáde,tí o ń fí wọ́n sùn níwájú Ọlọ́run wa lọ́sàn-án àti lóru.
11 Wọ́n sì ti ṣẹ́gun rẹ̀nítorí ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́-Àgùntàn náà,àti nítorí ọ̀rọ̀ ẹ̀rí wọn,wọn kò sì fẹ́ràn ẹ̀míwọn àní títí dé ikú.
12 Nítorí náà ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin ọ̀run,àti ẹ̀yin tí ń gbé inú wọn.Ègbé ni fún ayé àti òkun;nítorí Èṣù sọ̀kalẹ̀ tọ̀ yín wá ní ìbínú ńlá,nítorí ó mọ̀ pé ìgbà kúkúrú ṣá ni òun ní.”
13 Nígbà tí dírágónì náà rí pé a lé òun lọ sí ilẹ ayé, ó sè inúnibíni sì obìnrin tí ó bí ọmọkùnrin náà.
14 A sì fi apá iyẹ́ méjì tí ìdì ńlá náà fún obìnrin náà, pé kí ó fò lọ sí ihà, sí ipò rẹ̀, níbi tí a ó gbe bọ ọ fún àkókò kan àti fún àwọn àkókò, àti fún ìdajì àkókò kúrò lọ́dọ̀ ejò náà.
15 Ejò náà sì tu omi jáde láti ẹnu rẹ̀ wá bí odò ńlá sẹ́yìn obìnrin náà ki o lè fí ìṣàn omi náà gbà á lọ.
16 Ilẹ̀ sì ran obìnrin náà lọ́wọ́, ilẹ́ sì ya ẹnu rẹ̀, ó sì fi ìṣàn omi náà mú, tí dírágónì náà tu jáde láti ẹnu rẹ̀ wá.
17 Dírágónì náà sì bínú gidigidi sí obìnrin náà, ó sì lọ bá àwọn irú ọmọ rẹ̀ ìyókù jagun, tí wọ́n ń pa òfin Ọlọ́run mọ̀, tí wọn sì di ẹ̀rí Jésù mú, Ó sì dúró lórí ìyanrìn òkun.