Ìfihàn 19 BMY

Halelúyà

1 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí mo gbọ́ ohùn ńlá ní ọ̀run bí ẹni pé tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, ń wí pé:“Halelúyà!Ti Olúwa Ọlọ́run wa ni ìgbàlà, àti ọlá agbára,

2 nítorí òtítọ́ àti òdodo ni ìdájọ́ rẹ̀.Nítorí o ti ṣe ìdájọ́ àgbèrè ńlá a nì,tí o fi àgbèrè rẹ̀ ba ilẹ́ ayé jẹ́, ó sì ti gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ náà.”

3 Àti lẹ́ẹ̀kejì wọ́n wí pé:“Halelúyà!Èéfín rẹ̀ sì gòkè lọ láé àti láéláé.”

4 Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún nì, àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin nì sì wólẹ, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run tí ó jókòó lórí ìtẹ́, wí pé:“Àmín, Halelúyà!”

5 Ohùn kan sì ti ibi ìtẹ́ náà jáde wá, wí pé:“Ẹ máa yin Ọlọ́run wa,ẹ̀yin ìránṣẹ́ rẹ̀ gbogbo,ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù rẹ̀,àti èwe àti àgbà!”

6 Mo sì gbọ́ bí ẹni pé ohùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àti bí ìró omi púpọ̀, àti bí ìró àrá ńláńlá, ń wí pé:“Halelúyà!Nítorí Olúwa Ọlọ́run wa, Olódùmarè ń jọba.

7 Ẹ jẹ́ kí a yọ̀, kí inú wa kí ó sì dùn gidigidi,kí a sì fi ògo fún un.Nítorí pé ìgbéyàwó Ọ̀dọ́-Àgùntàn dé,aya rẹ̀ sì ti múra tán.

8 Òun ni a sì fi fún pé kí ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀wíwẹ́ tí ó funfun gbòò.”(Nítorí pé aṣọ ọ̀gbọ̀ nì dúró fún iṣẹ́ òdodo àwọn ènìyàn mímọ́.)

9 Ó sì wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀, ‘Ìbùkún ni fún àwọn tí a pè sí àsè-alẹ́ ìgbéyàwó ọ̀dọ́-àgùntàn.’ ” Ó sì wí fún mi pé: “Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ òtítọ́ Ọlọ́run.”

10 Mo sì wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀ láti foríbalẹ̀ fún un. Ó sì wí fún mi pé, “Wò ó, má ṣe bẹ́ẹ̀: ìránṣẹ́ ẹlẹ́gbẹ́ rẹ̀ ni èmi, àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ tí wọ́n di ẹ̀rí Jésù mú: foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run: nítorí pé ẹ̀rí Jésù ni ìsọtẹ́lẹ̀.”

Ẹni Tó Gun Ẹsin Funfun

11 Mo sì rí ọ̀run sí sílẹ̀, sì wò ó, ẹsin funfun kan; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ni à ń pè ní Olódodo àti Olóòótọ́, nínú òdodo ni ó sì ń ṣe ìdájọ́, tí ó ń jagun.

12 Ojú rẹ̀ dàbí ọ̀wọ́ iná, àti ní orí rẹ̀ ni adé púpọ̀ wà; ó sì ní orúkọ kan tí a kọ, tí ẹnikẹ́ni kò mọ́, bí kò ṣe òun tìkárarẹ̀.

13 A sì wọ̀ ọ́ ní aṣọ tí a tẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀: a sì ń pe orúkọ rẹ̀ ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

14 Àwọn ogun tí ń bẹ ní ọrùn tí a wọ̀ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́, funfun àti mímọ́, sì ń tọ̀ ọ́ lẹ̀yìn lórí ẹ̀sin funfun.

15 Àti láti ẹnu rẹ̀ ni idà mímú ti ń jáde lọ, kí ó lè máa fi ṣá àwọn orílẹ̀-èdè: “Òun ó sì máa fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn:” ó sì ń tẹ ìfúntí àti ìbínú Ọlọ́run Olódùmarè.

16 Ó sì ní lára aṣọ rẹ̀ àti ni ìtàn rẹ̀ orúkọ kan tí a kọ:ỌBA ÀWỌN ỌBA ÀTI Olúwa ÀWỌN Olúwa

17 Mo sì rí ańgẹ́lì kan dúró nínú òòrùn; ó sì fi ohùn rara kígbe, ó ń wí fún gbogbo àwọn ẹyẹ tí ń fò ní agbede-méjì ọ̀run pé: “Ẹ wá ẹ sì kó ara yín jọ pọ̀ sí àsè-ńlá Ọlọ́run;

18 Kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ ẹran-ara àwọn ọba, àti ẹran-ara àwọn olórí ogun àti ẹran-ara àwọn ènìyàn alágbára, àti ẹran àwọn ẹsin, àti ti àwọn tí ó jókòó lórí wọn, àti ẹran-ara ènìyàn gbogbo, àti ti òmìnira, àti ti ẹrù, àti ti èwe àti ti àgbà.”

19 Mo sì rí ẹranko náà àti àwọn ọba ayé, àti àwọn ogun wọn tí a gbájọ láti bá ẹni tí ó jókòó lórí ẹsin náà àti ogun rẹ̀ jagun.

20 A sì mú ẹranko náà, àti wòlíì èké nì pẹ̀lú rẹ̀, tí ó ti ń ṣe iṣẹ́ ìyanu níwájú rẹ̀, èyí tí ó fi ń tan àwọn tí ó gba àmì ẹranko náà àti àwọn tí ń foríbalẹ̀ fún àwòrán rẹ̀ jẹ. Àwọn méjèèje yìí ni a sọ láàyè sínú adágún iná tí ń fi súfúrù jó.

21 Àwọn ìyókù ni a sì fi idà ẹni tí ó jókòó lórí ẹsin náà pa, àní idà tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde: Gbogbo àwọn ẹyẹ sì ti ipa ẹran ara wọn yó.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22