Ìfihàn 1 BMY

Ọ̀rọ̀ Ìsáájú

1 Ìfihàn ti Jésù Kírísítì, tí Ọlọ́run fi fún un, láti fi hàn fún àwọn ìranṣẹ́ rẹ̀, ohun tí kò le ṣàìsẹ ní lọ́ọ́lọ́; ó sì ránṣẹ́, ó sì fi í hàn láti ọwọ́ ańgẹ́lì rẹ̀ wá fún Jòhánù, ìránṣẹ́ rẹ̀:

2 Ẹni tí ó jẹ́rìí ohun gbogbo tí ó rí—èyí ì ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti ẹ̀rí ti Jésù Kírísítì.

3 Olúkúlùkù ni ẹni tí ń kà, àti àwọn tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ìsọtẹ̀lẹ̀ yìí, tí ó sì ń pa nǹkan wọ̀n-ọ́n-nì tí a kọ sínú rẹ̀ mọ́: nítorí ìgbà kù sí dẹ̀dẹ̀.

Ọ̀rọ̀ Ìkíni Àti Ìyìn

4 Jòhánù,Sí àwọn ìjọ méje tí ń bẹ ní Éṣíà:Ore-ọ̀fẹ́ fún yín, àti àlàáfíà, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ń bẹ, tí ó sì ti wà, tí ó sì ń bọ̀ wá; àti láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mí méje tí ń bẹ níwájú ìtẹ́ rẹ̀;

5 Àti láti ọ̀dọ̀ Jésù Kírísítì, ẹlẹ́rì olóòótọ́, àkọ́bí nínú àwọn òkú, àti aláṣẹ àwọn ọba ayé.Ẹni tí ó fẹ́ wa, ẹni tí gbà wá kúrò lọ́wọ́ ẹ̀sẹ̀ wa nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀,

6 Tí ó sì ti fi wá jẹ ọba àti àlùfáà láti sin Ọlọ́run àti Baba rẹ; tirẹ̀ ni ògo àti ìjọba láé àti láéláé. Àmín.

7 Kíyèsí i, Ó ń bọ̀ nínú àwọsánmọ̀;gbogbo ojú ni yóò sì rí i,àti àwọn tí ó gún un ní ọ̀kọ̀ pẹ̀lú;àti gbogbo orílẹ̀-èdè ayé ni yóò sì máa pohùnréré ẹkún nítorí rẹ̀.Bẹ́ẹ̀ náà ni. Àmín.

8 “Èmi ni Álfà àti Òmégà,” ni Olúwa Ọlọ́run wí, “ẹni tí ó ń bẹ, tí ó ti wà, tí ó sì ń bọ̀ wá, Olódùmarè.”

Ọ̀kan Gẹ́gẹ́ Bí Ọmọ Ènìyàn

9 Èmi, Jòhánù, arákùnrin yín àti alábàápín pẹ̀lú yín nínú wàhálà àti ìjọba àti sùúrù tí ń bẹ nínú Jésù, wà ní erekùsù tí a ń pè ní Patimo, nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti nítorí ẹ̀rí Jésù Kírísítì.

10 Mo wà nínú Ẹ̀mí ní ọjọ́ Olúwa, mo sì gbọ́ ohùn ńlá kan lẹ̀yìn mi, bí ìró ipè,

11 Ó ń wí pé, “Èyí tí ó wí pé, kọ̀wé rẹ̀, ohun tí ìwọ rí, kí ó sí fi ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ méje; sí Éfésù, àti sí Simirínà, àti sí Párágámù, àti sí Tíátírà, àti sí Sarádì, àti sí Filadéfíà, àti sí Laódíkéà.”

12 Mo sì yí padà láti wo ohùn tí ń bá mi sọ̀rọ̀. Nígbà tí mo yípadà, mo rí ọ̀pá fìtílà wúrà méje;

13 Àti láàrin àwọn ọ̀pá fìtílà náà, ẹnìkan tí ó dà bí “ọmọ ènìyàn,” tí a wọ̀ ní aṣọ tí ó kanlẹ̀ dé ẹṣẹ̀, tí a sì fi àmùrè wúrà dì ní ẹ̀gbẹ́.

14 Orí rẹ̀ àti irun rẹ̀ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú, ó funfun bí Sínóò; ojú rẹ̀ sì dàbí, ọwọ́ iná;

15 Ẹṣẹ̀ rẹ̀ sì dàbí idẹ dáradára, bí ẹni pé a dà á nínú ìléru; ohùn rẹ̀ sì dàbí ìró omi púpọ̀.

16 Ó sì ní ìràwọ̀ méje ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀; àti láti ẹnu rẹ̀ wá ni idà olójú méjì mímú ti jáde: Ojú rẹ̀ sì dàbí òòrùn tí ó ń fi agbára rẹ̀ hàn.

17 Nígbà tí mo rí i, mo wólẹ̀ ní ẹṣẹ̀ rẹ̀ bí ẹni tí ó kú. Ó si fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lé mi, ó ń wí fún mi pé, “Máṣe bẹ̀rù. Èmi ni ẹni-ìṣájú àti ẹni-ìkẹyìn.

18 Èmi ni ẹni tí ó ń bẹ láàyè, tí ó sì ti kú; sì kíyèsí i, èmi sì ń bẹ láàyè sí i títí láé! Mo sì ní kọ́kọ́rọ́ ikú àti ti ipò-òkú.

19 “Kọ̀wé nítorí náà ohun tí ìwọ ti rí, àti ti ohun tí ń bẹ, àti ti ohun tí yóò hù lẹ́yìn èyí;

20 Ohun ìjìnlẹ̀ tí ìràwọ̀ méje náà tí ìwọ rí ní ọwọ́ ọ̀tún mi, àti ọ̀pá wúrà fìtílà méje náà. Ìràwọ̀ méje ni àwọn ańgẹ́lì ìjọ méje náà: àti ọ̀pá fìtílà méje náà ní àwọn ìjọ méje.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22