1 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí mo sì rí ańgẹ́lì mìíràn, ó ń ti ọ̀run sọkalẹ̀ wá ti òun ti agbára ńlá; ilẹ̀ ayé sì ti ipa ògo rẹ̀ mọ́lẹ̀.
2 Ó sì kígbe ní ohùn rara, wí pé:“Bábílónì ńlá ṣubú! Ó ṣubú!Ó sì di ibùjókòó àwọn ẹ̀mí ẹ̀ṣù,àti ihò ẹ̀mí àìmọ́ gbogbo,àti ilé ẹyẹ àìmọ́ gbogbo,àti ti ẹyẹ ìríra.
3 Nítorí nípa ọtí wáìnì ìrunú àgbèrè rẹ̀ nigbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ṣubú.Àwọn ọba ayé sì ti bá a ṣe àgbèrè,àti àwọn oníṣòwò ayé sì di ọlọ́rọ̀ nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọ̀bìà rẹ̀.”
4 Mo sì gbọ́ ohùn mìíràn láti ọ̀run wá, wí pé:“Ẹ ti inú rẹ̀ jáde, ẹ̀yin ènìyàn mi,kí ẹ ma bàá ṣe alábàápín nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,kí ẹ ma bàá si ṣe gbà nínú ìyọnu rẹ̀.
5 Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ga títí dé ọ̀run,Ọlọ́run sì ti rántí àìsedédé rẹ̀.
6 San an fún un, àní bí òun tí san án fún ní,kí ó sì ṣe e ni ìlọ́po méjì fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀Nínú ago náà tí o ti kún, òun ni kí ẹ sì kún fún un ni méjì.
7 Níwọ̀n bí o ti yin ara rẹ̀ lógo tó,tí ó sì hùwà wọ̀bìà,níwọ̀n bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ dá a lóró kí ẹ sì fún un ní ìbànújẹ́;nítorí tí ó wí ní ọkàn rẹ̀ pé,‘Mo jókòó bí ọbabìnrin,èmi kì sì í ṣe opó, èmí kì yóò sì rí ìbànújẹ́ láé.’
8 Nítorí náà, ní ìjọ kan ni ìyọnu rẹ̀ yóò dé,ìkú, àti ìbìnújẹ́, àti ìyàn;a ó sì fi iná sun ún pátapáta:nítorí pé alágbára ni Olúwa Ọlọ́run tí ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀.
9 “Àti àwọn ọba ayé, tí ó ti ń bá a ṣe àgbérè, ti wọn sì ń hùwà wọ̀bìà, yóò sì pohùnréré ẹkún lé e lórí, nígbà tí wọn bá wo èéfín ìjóná rẹ̀.
10 Wọ́n ó dúró ní òkèrè réré nítorí ìbẹ̀rù iṣẹ́ oró rẹ̀, wọn ó máa wí pé:“ ‘Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá náà,Bábílónì ìlú alágbára nì!Nítorí ní wákàtí kan ni ìdájọ́ rẹ dé!’
11 “Àwọn oníṣòwò ayé sì ń sọkún, wọn sì ń sọ̀fọ̀ lórí rẹ̀, nítorí pé ẹnikẹ́ni kò rà ọjà wọn mọ́:
12 Ọjà wúrà, àti ti fàdákà, àti ti òkúta iyebíye, àti ti pẹ́rílì, àti ti aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́, àti tí elése àlùkò, àti ti sẹ́dà, àti ti òdòdó, àti ti gbogbo igi olóòórùn dídùn, àti ti olúkúlùkù ohun èlò tí a fi igi iyebíye ṣe, àti ti idẹ, àti ti irin, àti ti òkúta mabílì.
13 Àti ti Kínamónì, àti ti onírúurú ohun olóòórun dídùn, àti ti ohun ìkunra, àti tí tùràrí, àti ti ọtí wáìnì, àti ti oróro, àti ti ìyẹ̀fun dáradára, àti ti àlìkámà, àti ti ẹran ńlá, àti ti àgùntàn, àti ti ẹ̀sin, àti ti kẹ̀kẹ́, àti ti ẹrú, àti ti ọkàn ènìyàn.
14 “Àti àwọn èso tí ọkàn rẹ̀ ń ṣe. Ìfẹ́kufẹ̀ẹ́ sí, si lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ, àti ohun gbogbo tí ó dùn tí ó sì dára ṣègbé mọ́ ọ lójú, kì yóò sì tún rí wọn mọ́ láé.
15 Àwọn oníṣòwò nǹkan wọ̀nyí, tí a ti ipa rẹ̀ sọ di ọlọ́rọ̀, yóò dúró ní òkèrè rére nítorí ìbẹ̀rù iṣẹ oró rẹ̀, wọn o máa sọ́kún, wọ́n ó sì máa ṣọ̀fọ̀,
16 Wí pé:“ ‘Ẹ̀gbẹ́! Ẹ̀gbé, ni fún ìlú ńlá nì,tí a wọ̀ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́,àti ti elése àlùkò, àti ti òdòdó, àti ti a sì fi wúrà ṣe lọ́sọ̀ọ́, pẹ̀lú òkúta iyebíye àti pẹrílì!
17 Nítorí pé ní wákàtí kan ni ọrọ̀ ti o pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ di asán!’“Àti olúkulùkù ẹni tí ń rin ojú omi lọ sí ìbikíbí, àti àwọn ti ń ṣiṣẹ́ nínú ọkọ àwọn ti ń ṣòwò ojú òkun dúró ní òkèrè réré,
18 Wọ́n sì kígbe nígbà tí wọ́n rí èéfín jíjóná rẹ́, wí pé, ‘Ìlú wo ni o dàbí ìlú yìí?’
19 Wọ́n sì kú ekuru sí orí wọn, wọ́n kígbe, wọ́n sọkún, wọn sì ń ṣọ̀fọ̀, wí pé:“ ‘Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá náà,nínú èyí tí a sọ gbogbo àwọn tí ó ni ọkọ̀ní òkun di ọlọ́rọ̀ nípa ohun iyebíye rẹ̀!Nítorí pé ni wákàtí kan, a sọ ọ́ di ahoro.
20 Yọ̀ lórí rẹ̀, ìwọ ọ̀run!Àti ẹ̀yin Àpósítélì mímọ́ àti wòlíì!Nítorí Ọlọ́run ti gbẹ̀san yín lára rẹ̀.’ ”
21 Ańgẹ́lì alágbára kan sì gbé òkúta kan sókè, ó dàbí ọlọ ńlá, ó sì jù ú sínú òkun, wí pé:“Báyìí ní a ó fi agbára ńlábíi Bábílónì ìlú ńlá ni wó,a kì yóò sì rí i mọ́ láé.
22 Àti ohùn àwọn aludùùrù, àti ti àwọn olórin,àti ti àwọn afọnrèrè, àti ti àwọn afọ̀npè,ni a kì yóò sì gbọ́ nínú rẹ mọ́ rara;àti olukulùkù oníṣọ̀nà ohunkóhun ni a kì yóò sì rí nínú rẹ mọ́ láé:Àti ìró ọlọ ní a kì yóòsì gbọ́ mọ̀ nínú rẹ láé;
23 Àti ìmọ́lẹ̀ fìtílà ni kì yóò sì tàn nínú rẹ̀ mọ́ láé;a kì yóò sì gbọ́ ohùn ọkọ ìyàwó àti ti ìyàwó nínú rẹ mọ́ láé:nítorí pé àwọn oníṣòwò rẹ̀ ni àwọn ẹni ńlá ayé;nítorí pé nípa ọ̀ṣọ́ rẹ̀ ní a fi tàn orílẹ̀ èdè gbogbo jẹ.
24 Àti nínú rẹ̀ ní a gbé ri ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì,àti ti àwọn ènìyàn mímọ́, àti ti gbogbo àwọn tí a pa lórí ilẹ̀ ayé.”