Ìfihàn 14:8-14 BMY

8 Ańgẹ́lì mìíràn sì tẹ̀lé e, ó ń wí pé, “Ó ṣubú, Bábílónì ńlá ṣubú, èyí ti o tí ń mú gbogbo orílẹ̀-èdè mu nínú ọtí wáìnì àìmọ́ àgbèrè rẹ̀!”

9 Ańgẹ́lì mìíràn, ẹ̀kẹta, sì tẹ̀lé wọn, ó ń wí ni ohùn rara pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá ń fóríbalẹ̀ fún ẹranko náà àti àwòrán rẹ̀, tí ó sì gba àmì sí iwájú orí rẹ̀ tàbí sí ọwọ́ rẹ̀.

10 Òun pẹ̀lú yóò mú nínú ọtí-wáìnì ìbínú Ọlọ́run, tí a dà láìní àbùlà sínú ago ìrúnnú rẹ̀; a ó sì fi iná sufúrù dá a lóró níwájú àwọn ańgẹ́lì mímọ́, àti níwájú Ọ̀dọ́-Àgùntàn:

11 Èéfín ìdálóró wọn ń lọ sókè títí láéláé wọn kò sì ní ìsinmi ni ọ̀sán àti ní òru, àwọn tí ń foríbalẹ̀ fún ẹranko náà àti fún àwòrán rẹ̀, àti ẹnikẹ́ni tí o ba sì gba àmì orúkọ rẹ̀.”

12 Nihìn-ín ni sùúrù àwọn ènìyàn mímọ́ gbé wà: àwọn tí ń pa òfin Ọlọ́run àti ìgbàgbọ́ Jésù mọ́.

13 Mo sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run wá ń wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀: Alábùkún fún ni àwọn òkú tí o kú nínú Olúwa láti ìhín lọ.”Alábùkún ni wọ́n nítòótọ́, bẹ́ẹ̀ ni, Ẹ̀mí wí, “Nítorí tí wọn yóò sìnmí kúrò nínú làálàá wọn, nítorí iṣẹ́ wọn ń tọ̀ wọn lẹ́yìn.”

14 Mo sì wo, sì kíyèsi i, ìkúùkùu àwọsánmà funfun kan, àti lóri ìkúùkùu àwọ̀sánmà náà ẹnikan jókòó tí o “dàbí Ọmọ ènìyàn,” tí òun ti adé wúrà ní orí rẹ̀, àti dòjé mímú ni ọwọ́ rẹ̀.