1 Mo sì gbọ́ ohùn ńlá kan láti inú tẹ́ḿpìlì wá, ń wí fún àwọn ańgẹ́lì, méje nì pé, “Ẹ lọ, ẹ sì tú ìgò ìbínú Ọlọ́run wọ̀nnì sí orí ayé.”
2 Èkínní sì lọ, ó sì tú ìgò tirẹ̀ sí orílẹ̀ ayé: egbò kíkẹ̀ tí ó sì díbàjẹ́ sì dá àwọn ènìyàn tí ó ní àmì ẹranko náà, àti àwọn tí ń foríbalẹ̀ fún àwòrán rẹ̀.
3 Èkejì sì tú ìgò sínú òkun; ó sì dàbí ẹ̀jẹ̀ òkú ènìyàn: gbogbo ọkàn alàyè sì kú nínú òkun.
4 Ẹ̀kẹ́ta sì tú ìgò tirẹ̀ sínú odò, àti sí orísun àwọn omi; wọ́n sì di ẹ̀jẹ̀.