10 Ẹ̀karùn-ún sì tú ìgo tirẹ̀ sórí ìtẹ ẹranko náà; ilẹ̀ ọba rẹ̀ sì sókùnkùn; wọ́n sì ń gé ahọ́n wọn jẹ́ nítorí ìrora.
11 Wọ́n sì sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run ọ̀run nítorí ìrora wọn àti nítorí egbò wọn, wọ́n kò sì ronupìwàdà iṣẹ́ wọn.
12 Ẹ̀kẹfà sì tu ìgò tirẹ̀ sórí odò ńlá Yúfúrátè; omi rẹ̀ sì gbẹ, kí a lè pèṣè ọ̀nà fún àwọn ọba láti ìlà òòrùn wá.
13 Mo sì rí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ mẹ́ta bí ọ̀pọ̀lọ́, wọ́n ti ẹnu dírágónì náà àti ẹnu ẹranko náà àti ẹnu wòlíì èké náà jáde wá.
14 Nítorí ẹ̀mí èṣù ni wọ́n, tí ń ṣe iṣẹ́ ìyanu, àwọn tí ń jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé, láti gbá wọn jọ sí ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olúdàmarè.
15 “Kíyèsí i; ń bọ̀ bi olè, ìbùkún ni fún ẹni tí ń sọ́nà, tí ó sì ń pa aṣọ rẹ̀ mọ́, kí ó mà bàá rìn ni ìhóhò, wọn a sì rí ìtìjú rẹ̀.”
16 Ó sì gbá wọn jọ́ sí ìbikan tí a ń pè ní Ámágédónì ní èdè Hébérù.