12 Ẹ̀kẹfà sì tu ìgò tirẹ̀ sórí odò ńlá Yúfúrátè; omi rẹ̀ sì gbẹ, kí a lè pèṣè ọ̀nà fún àwọn ọba láti ìlà òòrùn wá.
13 Mo sì rí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ mẹ́ta bí ọ̀pọ̀lọ́, wọ́n ti ẹnu dírágónì náà àti ẹnu ẹranko náà àti ẹnu wòlíì èké náà jáde wá.
14 Nítorí ẹ̀mí èṣù ni wọ́n, tí ń ṣe iṣẹ́ ìyanu, àwọn tí ń jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé, láti gbá wọn jọ sí ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olúdàmarè.
15 “Kíyèsí i; ń bọ̀ bi olè, ìbùkún ni fún ẹni tí ń sọ́nà, tí ó sì ń pa aṣọ rẹ̀ mọ́, kí ó mà bàá rìn ni ìhóhò, wọn a sì rí ìtìjú rẹ̀.”
16 Ó sì gbá wọn jọ́ sí ìbikan tí a ń pè ní Ámágédónì ní èdè Hébérù.
17 Èkeje si tú ìgo tírẹ̀ sí ojú ọ̀run; ohùn ńlá kan sì ti inú tẹ́ḿpìlì jáde láti ibi ìtẹ́, wí pé, “Ó parí!”
18 Mọ̀nàmọ́ná sì kọ, a sì gbọ́ ohùn, àrá sì sán, ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá sì ṣẹ̀, irú èyí tí kò sẹ̀ ri láti ìgbà tí ènìyàn ti wà lórí ilẹ̀, irú ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá bẹ́ẹ̀, tí ó sì lágbára tóbẹ́ẹ̀.