3 Èkejì sì tú ìgò sínú òkun; ó sì dàbí ẹ̀jẹ̀ òkú ènìyàn: gbogbo ọkàn alàyè sì kú nínú òkun.
4 Ẹ̀kẹ́ta sì tú ìgò tirẹ̀ sínú odò, àti sí orísun àwọn omi; wọ́n sì di ẹ̀jẹ̀.
5 Mo sì gbọ́ ańgẹ́lì ti omi wí pé:“Olódodo ni ìwọ Ẹni Mímọ́ ẹni tí ó ń bẹ,tí ó sì ti wà,nítorí tí ìwọ ṣe ìdájọ́ báyìí.
6 Nítorí tí wọ́n ti ta ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ àti ti àwọn wòlíì sílẹ̀,ìwọ sì fi ẹ̀jẹ̀ fún wọn mu; èyí yìí ní ó yẹ wọ́n.”
7 Mo sì gbọ́ pẹpẹ ń ké wí pé:“Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè,òtítọ́ àti òdodo ní ìdájọ́ rẹ.”
8 Ẹ̀kẹrin sì tú ìgò tirẹ̀ sórí oòrùn; a sì yọ̀ǹda fún un láti fi iná jó ènìyàn lára.
9 A sì fi oru ńlá jó àwọn ènìyàn lára, wọ́n sì sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ Ọlọ́run, ẹni tí ó ní agbára lórí ìyọnu wọ̀nyí: wọn kò sì ronúpìwàdà láti fi ògo fún un.