Ìfihàn 2:14-20 BMY

14 Ṣùgbọ́n mo ni nǹkan díẹ̀ wí sí ọ; nítorí tí ìwọ ní àwọn kan tí o di ẹ̀kọ́ Báláámù mú nibẹ̀, ẹni tí ó kọ́ Bálákì láti mú ohun ìkọ̀sẹ̀ wá ṣíwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, láti máa jẹ ohun tí a pa rúbọ sí òrìṣà, àti láti máa ṣe àgbèrè.

15 Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ sì ní àwọn tí ó gbá ẹ̀kọ́ àwọn Nikoláétanì pẹ̀lú, ohun tí mo kórìíra.

16 Nítorí náàonúpìwàdà; bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó tọ̀ ọ́ wá nísinsinyìí, èmí o sì fi idà ẹnu mi bá wọn jà.

17 Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ; Ẹni tí o bá ṣẹ́gun ni èmi o fi mánà tí ó pamọ́ fún, èmi ó sì fún un ni òkúta funfun kan, àti sára òkúta náà ni a kọ orúkọ tuntun kan, tí ẹnìkan kò mọ̀ bí kò ṣe ẹni tí ó gbà á.

18 “Àti sí Ańgẹ́lì ìjọ ní Tíátírà kọ̀wé:Nǹkan wọ̀nyí ni Ọmọ Ọlọ́run wí, ẹni tí ojú rẹ̀ dàbí ọ̀wọ́ iná, tí ẹṣẹ̀ rẹ̀ sì dàbí idẹ dáradára:

19 Èmi mọ̀ iṣẹ́, ìfẹ́, àti ìgbàgbọ́ àti ìsìn àti sùúrù rẹ̀; àti pé iṣẹ́ rẹ̀ ìkẹyìn ju tí iṣàájú lọ.

20 Ṣùgbọ́n èyí ni mo rí wí sì ọ: Nítorí tí ìwọ fi àyè sílẹ̀ fún obìnrin Jésébẹ́lì tí ó ń pe ara rẹ̀ ní wòlíì. Nípaṣ ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó sì ń kọ́ àwọn ìránṣẹ́ mi, ó sì ń tàn wọ́n láti máa ṣe àgbèrè, àti láti máa jẹ ohun tí a pa rúbọ sì òrìṣà.