2 Èmi mọ iṣẹ́ rẹ, àti làálàá rẹ, àti ìfaradà rẹ, àti bí ara rẹ kò ti gba àwọn ẹni búburú: àti bí ìwọ sì ti dán àwọn tí ń pe ara wọn ní àpósítélì, tí wọ́n kì í sì í se bẹ́ẹ̀ wo, tí ìwọ sì rí pé èké ni wọ́n;
3 Tí ìwọ sì faradà ìyà, àti nítorí orúkọ mi tí ó sì rọjú, tí àárẹ̀ kò sì mú ọ.
4 Ṣíbẹ̀ èyí ni mo rí wí sí ọ, pé, ìwọ ti fi ìfẹ́ ìṣáájú rẹsílẹ̀.
5 Rántí ibi tí ìwọ ti gbé subú! Ronúpìwàdà, kí ó sì ṣe iṣẹ́ ìsáájú; bí kò sì ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó sì tọ̀ ọ́ wá, èmi ó sì sí ọ̀pá fìtílà rẹ̀ kúrò ní ipò rẹ̀, bí kò ṣe bí ìwọ bá ronúpìwàdà.
6 Ṣùgbọ́n èyí ni ìwọ ní, pé ìwọ kórìíra ìṣe àwọn Nikoláétánì, èyí tí èmi pẹ̀lú sì kórìíra.
7 Ẹni tí ó bá ní etí kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mi ń sọ fún àwọn ìjọ. Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun ni èmi yóò fi èso igi ìye nì fún jẹ, tí ń bẹ láàrin Párádísè Ọlọ́run.
8 “Àti sí Ańgẹ́lì Ìjọ ní Símírínà Kọ̀wé:Nǹkan wọ̀nyí ni ẹni tí í ṣe ẹni-ìṣáájú àti ẹni-ìkẹyìn wí, ẹni tí ó ti kú, tí ó sì tún yè: