8 Èmi, Jòhánù, ni ẹni tí ó gbọ́ tí ó sì ri nǹkan wọ̀nyí. Nígbà tí mo sì gbọ́ tí mo sì rí, mo wólẹ̀ láti foríbalẹ̀ níwájú ẹsẹ̀ ańgẹ́lì náà, tí o fí nǹkan wọ̀nyí hàn mi,
9 Nígbà náà ni ó wí fún mi pé, “Wó ò, má ṣe bẹ́ẹ̀: ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ ni èmi, àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ wòlíì, àti ti àwọn tí ń pa ọ̀rọ̀ inú ìwé yìí mọ́: foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run!”
10 Ó sì wí fún mi pé, “Má ṣe fi èdìdì di ọ̀rọ̀ ìṣọtẹ́lẹ̀ tí inú ìwé yìí: nítorí ìgbà kù sí dẹ̀dẹ̀.
11 Ẹni tí ń ṣe aláìṣòótọ́, kí ó máa ṣe aláìṣòótọ́ nì ṣó: Àti ẹni tí ń ṣe ẹlẹ́gbin, kí ó máa ṣe ẹ̀gbin nìṣó: Àti ẹni tí ń ṣe olòdodo, kí ó máa ṣe òdodo nìṣó: Àti ẹni tí ń ṣe mímọ́, kí ó máa ṣe mímọ́ nìṣó.”
12 “Kíyèsí i, èmi ń bọ̀ kánkán; èrè mí sì ń bẹ pẹ̀lú mi, láti sán fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ yóò tí rí.
13 Èmi ni Álífà àti Òmégà, ẹni ìṣáájú àti ẹni ìkẹyìn, ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti òpin.
14 “Ìbùkún ni fún àwọn ti ń fọ aṣọ wọn, kí wọ́n lè ni àǹfààní láti wá sí ibi igi ìyè náà, àti kí wọ́n lè gbà àwọn ẹnu-bodè wọ inú ìlú náà.