1 “Àti sí Ańgẹ́lì ìjọ ni Sádísì kọ̀wé:Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ẹni tí ó ni Ẹ̀mí méje Ọlọ́run, àti ìràwọ̀ méje wí pé: Èmi mọ̀ iṣẹ́ rẹ̀, àti pé ìwọ ni orúkọ pé ìwọ ń bẹ láàyè, ṣùgbọ́n ìwọ ti kú.
2 Jí, kí o sì fi ẹsẹ̀ ohun tí ó kù múlẹ̀, tí ó ṣetán láti kú: Nítorí èmi kò rí iṣẹ́ rẹ ni pípé níwájú Ọlọ́run.
3 Nítorí náà rántí bí ìwọ ti gbà, àti bí ìwọ ti gbọ́, kí o sì pa á mọ́, kí o sì ronúpìwàdà. Ǹjẹ́, bí ìwọ kò ba ṣọ́ra, èmi yóò dé sí ọ bí olè, ìwọ kì yóò sì mọ́ wákàtí tí èmi yóò dé sí ọ.
4 Ìwọ ní orúkọ díẹ̀ ní Sádísì, tí kò fi aṣọ wọn yí èérí; wọn yóò sì máa ba mi rìn ní aṣọ funfun: nítorí wọ́n yẹ.