1 Mo sì rí i ni ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà, ìwé kan ti a kọ nínú àti lẹ̀yìn, ti a sì fi èdìdì méje dí.
2 Mó sì rí ańgẹ́lì alágbára kan, ó ń fi ohùn rara kéde pé, “Táni ó yẹ láti ṣí ìwé náà, àti láti tu èdìdì rẹ̀?”
3 Kò sì sí ẹni kan ní ọ̀run, tàbí lórí ilẹ̀ ayé, tàbí nísàlẹ̀ ilẹ̀, tí ó le ṣí ìwé náà, tàbí ti o lè wo inú rẹ̀.
4 Èmi sì sọkùn gidigidi, nítorí tí a kò ri ẹnìkan tí o yẹ láti sí i àti láti ka ìwé náà, tàbí láti wo inú rẹ̀.
5 Ọ̀kan nínú àwọn àgbà náà sì wí fún mi pé, “Má ṣe sọkún: kíyèsí i, kìnnìún ẹ̀yà Júdà, Gbòǹgbò Dáfídì, tí borí láti ṣí ìwé náà, àti láti tú èdìdì rẹ̀ méjèèje.”