1 Lẹ́yìn èyí ni mo rí ańgẹ́lì mẹ́rin dúró ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé, wọ́n di afẹ́fẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé mú, kí ó má ṣe fẹ́ sórí ilẹ̀, tàbí sórí òkun, tàbí sára igikígi.
2 Mo sì rí ańgẹ́lì mìíràn tí ó ń ti ìhà ìlà-òòrùn gòkè wá, ti òun ti èdìdì Ọlọ́run alààyè lọ́wọ́: ó sì kígbe ní ohùn rara sí àwọn ańgẹ́lì mẹ́rin náà tí a fifún un láti pa ayé, àti òkun, lára,
3 Wí pé, “Ẹ má ṣe pa ayé, tàbí òkun, tàbí igi lára, títí àwa ó fi fi èdìdì sàmì sí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run wa ní iwájú wọn.”
4 Mo sì gbọ́ iye àwọn tí a fi èdìdì sàmì si: Àwọn tí a sàmì sí jẹ́ ọ̀kẹ́ méje o lé ẹgbàájì láti inú gbogbo ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá.
5 Láti inú ẹ̀yà Júdà a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà.Láti inú ẹ̀yà Reubẹ́nì a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà.Láti inú ẹ̀yà Gádì a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà.