22 Ó sì jẹ́ àjọ̀dún ìyàsímímọ́ ní Jérúsálẹ́mù, ìgbà òtútù ni.
23 Jésù sì ń rìn ní tẹ́mpílì, ní ìloro Sólómónì,
24 Nítorí náà àwọn Júù wá dúró yí i ká, wọ́n sì wí fún un pé, “Ìwọ ó ti mú wa ṣe iyèméjì pẹ́ tó? Bí ìwọ bá ni Kírísítì náà, wí fún wa gbangba.”
25 Jésù dá wọn lóhùn pé, “Èmi ti wí fún yín, ẹ̀yin kò sì gbàgbọ́; iṣẹ́ tí èmi ń ṣe lórúkọ Baba mi, àwọn ni ó ń jẹ́rìí mi.
26 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbàgbọ́, nítorí ẹ̀yin kò sí nínú àwọn àgùntàn mi, gẹ́gẹ́ bí mo tí wí fún yín.
27 Àwọn àgùntàn mi ń gbọ́ ohùn mi, èmi sì mọ̀ wọ́n, wọn a sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn:
28 Èmi sì fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun; wọn kì yóò sì ṣègbé láéláé, kò sí ẹni tí ó lè já wọn gbà kúrò lọ́wọ́ mi.