1 Ǹjẹ́ kí àjọ ìrékọjá tó dé, nígbà tí Jésù mọ̀ pé, wákàtí rẹ̀ dé tan, tí òun ó ti ayé yìí kúrò lọ sọ́dọ̀ Baba, fífẹ́ tí ó fẹ́ àwọn tirẹ̀ tí ó wà ní ayé, ó fẹ́ wọn títí dé òpin.
2 Bí wọ́n sì ti ń jẹ oúnjẹ alẹ́, tí èṣù ti fi í sí ọkàn Júdásì Isíkáríótù ọmọ Símónì láti fi í hàn;
3 Tí Jésù sì ti mọ̀ pé Baba ti fi ohun gbogbo lé òun lọ́wọ́, àti pé lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni òun ti wá, òun sì ń lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run;
4 Ó dìde ní ìdí oúnjẹ alẹ́, ó sì fi agbádá rẹ̀ lélẹ̀ ní apákan; nígbà tí ó sì mú asọ ìnura, ó di ara rẹ̀ ní àmùrè.
5 Lẹ́yìn náà, ó bu omi sínú àwòkòtò kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í máa wẹ ẹṣẹ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì ń fi aṣọ ìnura tí ó fi di àmùrè nù wọ́n.
6 Nígbà náà ni ó dé ọ̀dọ̀ Símónì Pétérù, òun sì wí fún un pé, “Olúwa, ìwọ yóò ha wẹ ẹsẹ̀ mi?”
7 Jésù dá a lóhùn, ó sì wí fún un pé, “Ohun tí èmi ń ṣe ni ìwọ kò mọ̀ nísinsin yìí; ṣùgbọ́n yóò yé ọ ní ìkẹyìn.”
8 Pétérù wí fún un pé, “Ìwọ kì yóò wẹ̀ mí ní ẹṣẹ̀.” Jésù sì da lóhùn pé, “Bí èmi kò bá wẹ̀ ọ́, ìwọ kò ní ìpín ní ọ̀dọ̀ mi.”
9 Símónì Pétérù wí fún ún pé, “Olúwa, kì í ṣe ẹṣẹ̀ mi nìkan, ṣùgbọ́n àti ọwọ́ àti orí mi pẹ̀lú.”
10 Jésù wí fún un pé, “Ẹni tí a wẹ̀ kò tún fẹ́ ju kí a san ẹṣẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó mọ́ níbi gbogbo: ẹ̀yin sì mọ́, ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo yín.”
11 Nítorí tí ó mọ ẹni tí yóò fi òun hàn; nítorí náà ni ó se wí pé, Kìí ṣe gbogbo yín ni ó mọ́
12 Nítorí náà lẹ́yìn tí ó wẹ ẹṣẹ̀ wọn tán, tí ó sì ti mú agbádá rẹ̀, tí ó tún jókòó, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin mọ ohun tí mo ṣe sí yín bí?
13 Ẹ̀yin ń pè mí ní ‘Olùkọ́’ àti ‘Olúwa’: ẹ̀yin wí rere; bẹ́ẹ̀ ni mo jẹ́.
14 Ǹjẹ́ bí èmi tí í ṣe Olúwa àti Olùkọ́ yín bá wẹ ẹsẹ̀ yín, ó tọ́ kí ẹ̀yin pẹ̀lú sì máa wẹ ẹṣẹ̀ ara yín.
15 Nítorí mo fi àpẹẹrẹ fún yín, kí ẹ̀yin lè máa ṣe gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe sí yín.
16 Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ọmọ-ọ̀dọ̀ kò tóbi ju ọ̀gá rẹ̀ lọ, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí a rán kò tóbi ju ẹni tí ó rán an lọ.
17 Bí ẹ̀yin bá mọ nǹkan wọ̀nyí, alábùkún fún ni yín, bí ẹ̀yin bá ń se wọ́n!
18 “Kì í ṣe ti gbogbo yín ni mo ń sọ: èmi mọ àwọn tí mo yàn: ṣùgbọ́n kí ìwé-mímọ́ bá à lè ṣẹ, ‘Ẹni tí ń bá mi jẹun pọ̀ sì gbé gìgísẹ̀ rẹ̀ sí mi.’
19 “Láti ìsinsìn yìí lọ ni mo wí fún un yín kí ó tó dé, pé nígbà tí ó bá dé, kí ẹ̀yin lè gbàgbọ́ pé èmi ni.
20 Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, Ẹni tí ó bá gba ẹnikẹ́ni tí mo rán, ó gbà mí; Ẹni tí ó bá sì gbà mí, ó gba ẹni tí ó rán mi.”
21 Nígbà tí Jésù ti wí nǹkan wọ̀nyí tán, ọkàn rẹ̀ dàrú nínú rẹ̀, ó sì jẹ́rìí, ó sì wí pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún un yín pé, ọ̀kan nínú yín yóò dà mí.”
22 Àwọn ọmọ ẹ̀yin rẹ̀ ń wò ara wọn lójú, wọ́n ń siyè méjì ti ẹni tí ó wí.
23 Ǹjẹ́ ẹnìkan rọ̀gbọ̀kú sí àyà Jésù, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ẹni tí Jésù fẹ́ràn.
24 Nítorí náà ni Símónì Pétérù sàpẹrẹ sí i, ó sì wí fún un pé, “Wí fún wa ti ẹni tí o ń sọ.”
25 Ẹni tí ó sún mọ àya rẹ̀ bí i léèrè wí pé, Olúwa, taa ni í se?
26 Nítorí náà Jésù dáhùn pé, “Òun náà ni, ẹni tí mo bá fi àkàrà fún nígbà tí mo bá fi run àwo.” Nígbà tí ó sì fi run ún tan, ó fi fún Júdásì Ísíkárótù ọmọ Símónì.
27 Ní kété tí Júdásì gba àkàrà náà ni Sátanì wọ inú rẹ̀ lọ.Nítorí náà Jésù wí fún un pé, “Ohun tí ìwọ ń se nì, yára ṣe é kánkán.”
28 Kò sì sí ẹnìkan níbi tábìlì tí ó mọ ìdí tí ó ṣe sọ èyí fún un.
29 Nítorí àwọn mìíràn nínú wọn rò pé, nitorí Júdásì ni ó ni àpò, ni Jésù fi wí fún un pé, Ra nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí a kò le ṣe aláìní fún àjọ náà; tàbí kí ó lè fi nǹkan fún àwọn talákà.
30 Nígbà tí ó sì ti gbà òkèlè náà tan, ó jáde lójúkan náà: òru sì ni.
31 Nítorí náà nígbà tí ó jáde lọ tan, Jésù wí pé, “Nísinsìn yìí ni a yin ọmọ-ènìyàn lógo, a sì yin Ọlọ́run lógo nínú rẹ̀.
32 Bí a bá yin Ọlọ́run lógo nínú rẹ̀, Ọlọ́run yóò sì yìn ín lógo nínú òun tìkára rẹ̀, yóò sì yìn ín lógo nísinsìn yìí.
33 “Ẹ̀yin ọmọ mi, nígbà díẹ̀ sí i ni èmi wà pẹ̀lú yín. Ẹ̀yin ó wá mi: àti gẹ́gẹ́ bí mo ti wí fún àwọn Júù pé, Níbití èmi gbé ń lọ, ẹ̀yin kì ó le wà; bẹ́ẹ̀ ni mo sì wí fún yín nísìnsìn yìí.
34 “Òfin titun kan ni mo fi fún yín, kí ẹ̀yin kí ó fẹ́ ọmọnìkejì yín; gẹ́gẹ́ bí èmi ti fẹ́ràn yín, kí ẹ̀yin kí ó sì lè fẹ́ràn ọmọnìkejì yín.
35 Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé, ọmọ-ẹ̀yìn mi ni ẹ̀yin ń se, nígbà tí ẹ̀yin bá ní ìfẹ́ sí ọmọ ẹnìkejì yín.”
36 Símónì Pétérù wí fún un pé, “Olúwa, níbo ni ìwọ ń lọ?”Jésù dá a lóhùn pé, “Níbi tí èmi ń lọ, ìwọ kì yóò lè tọ̀ mí nísinsin yìí; ṣùgbọ́n ìwọ yóò tọ̀ mí níkẹyìn.”
37 Pétérù wí fún un pé, “Olúwa èése tí èmi kò fi le tọ̀ ọ́ nísinsìn yìí? Èmi ó fi ẹ̀mi mi lélẹ̀ nítorí rẹ.”
38 Jésù da lóhùn wí pé, “Ìwọ ó ha fi ẹ̀mí rẹ lélẹ̀ nítorí mi? Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, àkùkọ kì yóò kọ, kí ìwọ kí ó tó ṣẹ́ mi nígbà mẹ́ta!