Jòhánù 4 BMY

Jésù Sọ̀rọ̀ Pẹ̀lú Obìnrin Ara Samáríà

1 Àwọn Farisí sì gbọ́ pé, Jésù ni, ó sì n ṣe ìtẹ̀bọmi fún àwọn ọmọ ẹyìn púpọ̀ ju Jóhánù lọ,

2 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù tìkararẹ̀ kò ṣe ìtẹ̀bọmibí kò ṣe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀,

3 Nígbà tí Olúwa mọ nípa èyí, Ó fi Jùdéà sílẹ̀, ó sì tún lọ sí Gálílì lẹ́ẹ̀kan si.

4 Òun sì ní láti kọjá láàárin Samaríà.

5 Nígbà náà ni ó dé ìlú Samaríà kan, tí a ń pè ní Síkárì, tí ó súnmọ́ etí ilẹ̀ oko tí Jákọ́bù ti fi fún Jóṣéfù, ọmọ rẹ̀.

6 Kànga Jákọ́bù sì wà níbẹ̀. Nítorí pé ó rẹ Jésù nítorí ìrìn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó jòkó létí kànga: ó sì jẹ́ ìwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́.

7 Obìrin kan, ará Samaríà sì wá láti fà omi: Jésù wí fún un pé fún mi mu.

8 (Nítorí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti lọ sí ìlú láti lọ ra ońjẹ.)

9 Obìnrin ará Samáríà náà sọ fún un pé, “Júù ni ẹ́ obìnrin ará Samáríà ni èmi. Eéti rí tí ìwọ ń bèèrè ohun mímu lọ́wọ́ mi?” (Nítorí tí àwọn Júù kì í bá àwọn ará Samaríà ṣe pọ̀.)

10 Jésù dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Ìbáṣepé ìwọ mọ ẹ̀bùn Ọlọ́run, ati ẹni tí ó wí fún ọ pé, fún mi mu, ìwọ ìbá sì ti bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀, Òun ìbá ti fi omi ìyè fún ọ.”

11 Obìnrin náà wí fún un pé, “Alàgbà, ìwọ kò ní nǹkan tí ìwọ ó fi fà omi, bẹ́ẹ̀ ni kànga náà jìn: Níbo ni ìwọ ó ti rí omi ìyè náà?

12 Ìwọ pọ̀ ju Jákọ́bù baba wa lọ bí, ẹni tí ó fún wa ní kànga náà, tí Òun tìkararẹ̀ mu nínú rẹ̀, àti àwọn ọmọ rẹ̀, àti àwọn ẹran rẹ̀?”

13 Jésù dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá mu nínú omi yìí, òrùngbẹ yóò tún gbẹ ẹ́:

14 Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá mu nínú omi tí èmi ó fí fún un, òrùngbẹ kì yóò gbẹ ẹ́ mọ́ láé; ṣùgbọ́n omi tí èmi ó fi fún un yóò di kànga omi nínú rẹ̀, tí yóò máa sun títí ayérayé.”

15 Obìnrin náà sì wí fún u pé, “Alàgbà, fún mi ní omi yìí, kí òùngbẹ kí ó má se gbẹ mí, kí èmi kí ó má sì wá máa pọn omi níbí.”

16 Jésù wí fún un pé, “Lọ pe ọkọ rẹ, kí ó sì padà wá sí ìhín yìí.”

17 Òbìnrin náà dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Èmi kò ní ọkọ. Jésù wí fún un pé, Ìwọ́ dáhùn dáradára pé, èmi kò ní ọkọ:

18 Nítorí tí ìwọ ti ní ọkọ márùn-ún rí; ọkùnrin tí ìwọ sì ní bá yìí kì í ṣe ọkọ rẹ. Ohun tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán yìí, òtítọ́ ni.”

19 Obìnrin náà wí fún un pé, “Alàgbà, mo wòye pé, wòlíì ni ìwọ ń ṣe.

20 Àwọn bàbá wa sìn lórí òkè yìí; ẹ̀yin sì wí pé, Jérúsálẹ́mù ni ibi tí ó yẹ tí à bá ti máa sìn.”

21 Jésù wí fún un pé, “Gbà mí gbọ́, obìnrin yìí, àkókò náà ń bọ̀, nígbà tí kì yóò se lórí òke yìí tàbí ní Jérúsálẹ́mù ni ẹ̀yin ó máa sin Baba.

22 Ẹ̀yin ń sin ohun tí ẹ̀yin kò mọ̀: àwa ń sin ohun tí àwa mọ̀: nítorí ìgbàlà ti ọ̀dọ̀ àwọn Júù wá.

23 Ṣùgbọ́n àkókò ń bọ̀, ó sì dé tán nísinsìn yìí, nígbà tí àwọn olùsìn tòótọ́ yóò máa sin Baba ní ẹ̀mí àti ní òtítọ́: nítorí irú wọn ni Baba ń wá kí ó máa sin òun.

24 Ẹ̀mí ni Ọlọ́run: àwọn ẹni tí ń sìn ín kò lè ṣe aláìsìn ín ní ẹ̀mí àti ní òtítọ́.”

25 Obìnrin náà wí fún un pé, mo mọ̀ pé, “Mèsáyà ń bọ̀ wá, tí a ń pè ní Krísítì: Nígbà tí Òun bá dé, yóò sọ ohun gbogbo fún wa.”

26 Jésù sọ ọ́ di mímọ̀ fún un pé, “Èmi ẹni tí ń bá ọ sọ̀rọ̀ yìí ni Òun.”

Àwọn Ọmọ-Ẹ̀yìn Pẹ̀lú Jésù

27 Lórí èyí ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ dé, ẹnu sì yà wọ́n pé ó ń bá obìnrin sọ̀rọ̀: ṣùgbọ́n kò sí ẹnì kan tí ó wí pé, “Kíni ìwọ ń wá?” tàbí “Èéṣe tí ìwọ fi ń bá a sọ̀rọ̀?”

28 Nígbà náà ni obìnrin náà fi ládugbó rẹ̀ sílẹ̀, ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n lọ sí ìlú, ó sì wí fún àwọn ènìyàn pé,

29 “Ẹ wá wò ọkùnrin kan, ẹni tí ó sọ ohun gbogbo tí mo ti ṣe rí fún mi: èyí ha lè jẹ́ Krísítì náà?”

30 Nígbà náà ni wọ́n ti ìlú jáde, wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá.

31 Láàárin èyí, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń rọ̀ ọ́ wí pé, “Olùkọ́, jẹun.”

32 Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, “Èmi ní ońjẹ láti jẹ, tí ẹ̀yin kò mọ̀.”

33 Nítorí náà ni àwọn ọmọ-èyìn rẹ̀ ń bi ara wọn lérè wí pé, “Ẹnì kan mú ońjẹ fún un wá láti jẹ bí?”

34 Jésù wí fún wọn pé, “Ońjẹ mi ni láti ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi, àti láti parí iṣẹ́ rẹ̀.

35 Ẹ̀yin kò ha wí pé, ‘Ó ku oṣù mẹ́rin, ìkọ́rè yóò sì dé?’ Wò ó, mo wí fún un yín, Ẹ sí ojú yín sókè, kí ẹ sì wo oko; nítorí tí wọn ti pọ́n fún ìkórè.

36 Kódà báyìí, ẹni tí ó ń kórè ń gba owó ọ̀yà rẹ̀, kódà báyìí, ó ń kórè fún ayérayé: kí ẹni tí ó ń fúrúgìn àti ẹni tí ń kórè lè jọ máa yọ̀ pọ̀.

37 Nítorí nínú èyí ni ọ̀rọ̀ náà fi jẹ́ òtítọ́: Ẹnì kan ni ó fúrúgbìn, ẹlòmíràn ni ó sì ń kórè jọ.

38 Mo rán yín lọ kórè ohun tí ẹ kò ṣiṣẹ́ fún. Àwọn ẹlòmíràn ti ṣiṣẹ́, ẹ̀yin sì kórè èrè làálàá wọn.”

Ọ̀pọ̀ Ara Samáríà Gbàgbọ́

39 Ọ̀pọ̀ àwọn ará Samáríà láti ìlú náà wá sì gbà á gbọ́ nítorí ìjẹ́rìí obìnrin náà pé, “Ó sọ gbogbo ohun tí mo ti ṣe fún mi.”

40 Nítorí náà, nígbà tí àwọn ará Samáríà wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n rọ̀ ọ́ pé, kí ó wà pẹ̀lú wọn: ó sì dúró fún ijọ́ méjì.

41 Àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì gbàgbọ́ sí i nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

42 Wọ́n sì wí fún obìnrin náà pé, “Kì í ṣe nítorí ọ̀rọ̀ rẹ nìkan ni àwa ṣe gbàgbọ́: nítorí tí àwa tìkára wa ti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, àwa sì mọ̀ pé, nítòótọ́ èyí ni Krísítì náà, Olùgbàlà aráyé.”

Jésù Wọ Ọmọkùnrin Ọlọ́lá San

43 Lẹ́yìn ijọ́ méjì ó sì ti ibẹ̀ kúrò, ó lọ sí Gálílì.

44 (Nítorí Jésù tìkararẹ̀ ti jẹ́rìí wí pé, Wòlíì kì í ní ọlá ní ilẹ̀ Òun tìkárarẹ̀.)

45 Nítorí náà nígbà tí ó dé Gálílì, àwọn ará Gálílì gbà á, nítorí ti wọ́n ti rí ohun gbogbo tí ó ṣe ní Jérúsálẹ́mù nígbà àjọ; nítorí àwọn tìkára wọn lọ sí àjọ pẹ̀lú.

46 Bẹ́ẹ̀ ni Jésù tún wá sí Kánà ti Gálílì, níbi tí ó gbé sọ omi di wáìnì. Ọkùnrin ọlọ́lá kan sì wá, ẹni tí ara ọmọ rẹ̀ kò dá ní Kápérnámù.

47 Nígbà tí ó gbọ́ pé Jésù ti Jùdéà wá sí Gálílì, ó tọ̀ ọ́ wá, ó sì ń bẹ̀ ẹ́, kí ó lè sọ̀kalẹ̀ wá kí ó mú ọmọ òun láradá: nítorí tí ó wà ní ojú ikú.

48 Nígbà náà ni Jésù wí fún u pé, “Bí kò ṣe pé ẹ̀yin bá rí àmì àti iṣẹ́ ìyanu, ẹ̀yin kì yóò gbàgbọ́ láé.”

49 Ọkùnrin ọlọ́lá náà wí fún un pé, “Olúwa, sọ̀kalẹ̀ wá kí ọmọ mi tó kú.”

50 Jésù wí fún un pé, “Má a bá ọ̀nà rẹ lọ; ọmọ rẹ yóò yè.”

51 Bí ó sì ti ń sọ̀kalẹ̀ lọ, àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pàde rẹ̀, wọ́n sì wí fún un pé, ọmọ rẹ ti yè.

52 Nígbà náà ni ó béèrè wákàtí tí ara rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í yá lọ́wọ́ wọn, wọ́n sì wí fún un pé, “Ní àná, ní wákàtí kéje ni ibà náà fi í sílẹ̀.”

53 Bẹ́ẹ̀ ni baba náà mọ̀ pé ọmọ rẹ̀ yè: Òun tìkara rẹ̀ sì gbàgbọ́, àti gbogbo ilé rẹ̀.

54 Èyí ni iṣẹ́ àmì kéjì tí Jésù ṣe nígbà tí ó ti Jùdéà jáde wá sí Gálílì.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21