Jòhánù 2 BMY

Jésù Sọ Omi Di Ọtí Wáìnì

1 Ní ọjọ́ kẹ́ta, a ń ṣe ìgbéyàwó kan ní Kánà ti Gálílì. Ìyá Jésù sì wà níbẹ̀,

2 A sì pe Jésù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sí ibi ìgbéyàwó náà.

3 Nígbà tí wáìnì sì tán, ìyá Jésù wí fún un pé, “Wọn kò ní wáìnì mọ́.”

4 Jésù fèsì pé, “Arábìnrin ọ̀wọ́n, èése tí ọ̀rọ̀ yìí fi kàn mí? Àkókò mi kò tí ì dé.”

5 Ìyá rẹ̀ wí fún àwọn ìránṣẹ́ náà pé, “Ẹ ṣe ohunkóhun tí ó bá wí fún yín.”

6 Ìkòkò òkúta omi mẹ́fà ni a sì gbé kalẹ̀ níbẹ̀, irú èyí tí àwọn Júù máa ń fi ṣe ìwẹ̀nù, èyí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn gbà tó ìwọ̀n ogún sí ogójì gálọ́ọ̀nù.

7 Jésù wí fún àwọn ìránṣẹ́ náà pé, “Ẹ pọn omi kún ìkòkò wọ̀nyí.” Wọ́n sì pọn omi kún wọn títí dé etí.

8 Lẹ́yìn náà ni ó wí fún wọn pé, “Ẹ bù jáde lára rẹ̀ kí ẹ sì gbé e tọ olórí àsè lọ.”Wọ́n sì gbé e lọ;

9 Olórí àsè náà tọ́ omi tí a sọ di wáìnì wò. Òun kò sì mọ ibi tí ó ti wá, ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ tí ó bu omi náà wá mọ̀. Olórí àsè sì pe ọkọ ìyàwó sí apákan,

10 Ó sì wí fún un pé, “Olúkúlùkù a máa kọ́kọ́ gbé wáìnì tí ó dára jùlọ kalẹ̀; nígbà tí àwọn ènìyàn bá sì mu ún yó tan, nígbà náà níí wọ́n a mú èyí tí kò dára tó bẹ́ẹ̀ wá; ṣùgbọ́n ìwọ ti pa wáìnì dáradára yìí mọ́ títí ó fi di ìsinyìí.”

11 Èyí jẹ́ àkọ́se iṣẹ́ àmì rẹ̀, tí Jésù ṣe ní Kánà ti Gálílì. Ó sì fi ògo rẹ̀ hàn; àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì gbà á gbọ́.

Jésù Ṣe Àfọ̀mọ́ Tẹ́ḿpìlì

12 Lẹ́yìn èyí, ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí Kápérnámù, Òun àti Ìyá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀, àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀: wọ́n sì gbé ibẹ̀ ní ọjọ́ pípẹ́.

13 Àjọ-ìrékọjá àwọn Júù sì súnmọ́ etílé, Jésù sì gòkè lọ sí Jérúsálẹ́mù,

14 Ó sì rí àwọn tí n ta màlúù, àti àgùntàn, àti àdàbà, àti àwọn onípàsípàrọ̀ owó ní tẹ́ḿpìlì wọ́n jòko:

15 Ó sì fi okùn tẹ́ẹ́rẹ́ ṣe pàṣán, ó sì lé gbogbo wọn jáde kúrò nínú tẹ́ḿpílì, àti àgùntàn àti màlúù; ó sì da owó àwọn onípàṣípàrọ̀ owó nù, ó sì bi tábìlì wọn ṣubú.

16 Ó sì wí fún àwọn tí ń ta àdàbà pé, “Ẹ gbé nǹkan wọ̀nyí kúrò níhín; ẹ má ṣe sọ ilé Baba mi di ilé ọjà títà.”

17 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì rántí pé, a ti kọ ọ́ pé, “Ìtara ilé rẹ jẹ mí run.”

18 Nígbà náà ní àwọn Júù dáhùn, wọ́n sì bi í pé, “Àmì wo ni ìwọ lè fi hàn wá, tí ìwọ fi ń se nǹkan wọ̀nyí?”

19 Jésù dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ wó tẹ́ḿpílì yìí palẹ̀, Èmi ó sì tun un kọ ní ọjọ́ mẹ́ta.”

20 Nígbà náà ní àwọn Júù wí pé, “Ọdún mẹ́rìndíláàdọ́ta ni a fi kọ́ tẹ́ḿpílì yìí, ìwọ ó ha sì tún un kọ ní ijọ́ mẹ́ta?”

21 Ṣùgbọ́n Òun ń sọ ti tẹ́ḿpílì ara rẹ̀.

22 Nítorí náà nígbà tí ó jíǹde kúrò nínú òkú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ rántí pé, ó ti sọ èyí fún wọn; wọ́n sì gba ìwé Mímọ́, àti ọ̀rọ̀ tí Jésù ti sọ gbọ́.

23 Nígbà tí ó sì wà ní Jérúsálẹ́mù, ní àjọ-ìrékọjá, lákókò àjọ náà, ọ̀pọ̀ ènìyàn gba orúkọ rẹ̀ gbọ́ nígbà tí wọ́n rí iṣẹ́ àmì tí ó ṣe.

24 Ṣùgbọ́n Jésù kò gbé ara lé wọn, nítorí tí ó mọ gbogbo ènìyàn.

25 Òun kò sì nílò ẹ̀rí nípa ènìyàn: nítorí tí Ó mọ̀ ohun tí ń bẹ nínú ènìyàn.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21