Jòhánù 19 BMY

A Dá Jésù Lébí Láti Kàn Mọ Àgbélébùú

1 Nítorí náà ni Pílátù mú Jésù, ó sì nà án.

2 Àwọn ọmọ ogun sì hun adé ẹ̀gún, wọ́n sì fi dé e ní orí, wọ́n sì fi aṣọ ìgúnwà elésèé àlùkò wọ̀ ọ́.

3 Wọ́n sì wí pé, “Kábíyèsí, ọba àwọn Júù!” Wọ́n sì fi ọwọ́ wọn gbá a ní ojú.

4 Pílátù sì tún jáde, ó sì wí fún wọn pé, “Wò ó, mo mú u jáde tọ̀ yín wá, kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ pé, èmi kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́wọ́ rẹ̀.”

5 Nítorí náà Jésù jáde wá, ti òun ti adé ẹ̀gún àti aṣọ elésèé àlùkò. Pílátù sì wí fún wọn pé, Ẹ wò ọkùnrin náà!

6 Nítorí náà nígbà tí àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn oníṣẹ́ rí i, wọ́n kígbe wí pé, “Kàn án mọ́ àgbélébùú, kàn án mọ́ àgbélébùú.”Pílátù wí fún wọn pé, “Ẹ mú un fún ara yín, kí ẹ sì kàn án mọ́ àgbélébùú: nítorí èmi kò rí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀.”

7 Àwọn Júù dá a lóhùn wí pé, “Àwa ní òfin kan, àti gẹ́gẹ́ bí òfin, wa ó yẹ fún un láti kú, nítorí ó gbà pé ọmọ Ọlọ́run ni òun ń ṣe.”

8 Nítorí náà nígbà tí Pílátù gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀rù túbọ̀ bà á.

9 Ó sì tún wọ inú gbọ̀ngàn ìdájọ́ lọ, ó sì wí fún Jésù pé, “Níbo ni ìwọ ti wá?” Ṣùgbọ́n Jésù kò dá a lóhùn.

10 Nítorí náà, Pílátù wí fún un pé, “Èmi ni ìwọ kò fọhùn sí? Ìwọ kò mọ̀ pé, èmi ní agbára láti dá ọ sílẹ̀, èmi sì ní agbára láti kàn ọ́ mọ́ àgbélébùú?”

11 Jésù dá a lóhùn pé, “Ìwọ kì bá tí ní agbára kan lórí mi, bí kò se pé a fi í fún ọ láti òkè wá: nítorí náà ẹni tí ó fi mí lé ọ lọ́wọ́ ni ó ní ẹ̀ṣẹ̀ pọ̀ jù.”

12 Nítorí èyí Pílátù ń wá ọ̀nà láti dá a sílẹ̀: ṣùgbọ́n àwọn Júù kígbe, wí pé, “Bí ìwọ bá dá ọkùnrin yìí sílẹ̀, ìwọ kì í se ọ̀rẹ́ Késárì: ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ara rẹ̀ ní ọba, ó sọ̀rọ̀ òdì sí Késárì.”

13 Nítorí náà nígbà tí Pílátù gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó mú Jésù jáde wá, ó sì jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́ ní ibi tí a ń pè ní Òkúta-títẹ́, ṣùgbọ́n ní èdè Hébérù, Gábátà.

14 Ó jẹ́ ìpalẹ̀mọ́ Àjọ-ìrékọjá, ó sì jẹ́ ìwọ̀n wákàtí ẹ̀kẹfà:Ó sì wí fún àwọn Júù pé, “Ẹ wo ọba yín!”

15 Nítorí náà wọ́n kígbe wí pé, “Mú un kúrò, mú un kúrò. Kàn án mọ́ àgbélébùú.”Pílátù wí fún wọn pé, “Èmi yóò ha kan ọba yín mọ́ àgbélébùú bí?”Àwọn olórí àlùfáà dáhùn wí pé, “Àwa kò ní ọba bí kò ṣe Kábíyèsí.”

16 Nítorí náà ni ó fà á lé wọn lọ́wọ́ láti kàn án mọ́ àgbélébùú.

Wọ́n Kan Jésù Mọ́ Àgbélébùú

17 Nítorí náà, wọ́n mú Jésù, ó sì jáde lọ, ó ru àgbélébùú fúnra rẹ̀ sí ibi tí à ń pè ní ibi agbárí, ní èdè Hébérù tí à ń pè ní Gọlígọtà:

18 Níbití wọ́n gbé kàn án mọ́ àgbélébùú, àti àwọn méjì mìíràn pẹ̀lú rẹ̀, níhà ìhín àti níhà kejì, Jésù sì wà láàárin.

19 Pílátù sì kọ ìwé kan pẹ̀lú, ó sì fi í lé e lórí àgbélébùú náà. Ohun tí a sì kọ ni, JÉSÙ TI NÁSÁRẸ́TÌ ỌBA ÀWỌN JÚÙ.

20 Nítorí náà, ọ̀pọ̀ àwọn Júù ni ó ka ìwé àkọlé yìí: nítorí ibi tí a gbé kan Jésù mọ́ àgbélébùú sún mọ́ etí ìlú: a sì kọ ọ́ ní èdè Hébérù àti Látìnì, àti ti Gíríkì.

21 Nítorí náà àwọn olórí àlùfáà àwọn Júù wí fún Pílátù pé, “Má ṣe kọ, ‘Ọba àwọn Júù;’ ṣùgbọ́n pé ọkùnrin yìí wí pé, èmi ni Ọba àwọn Júù.”

22 Pílátù dáhùn pé, ohun tí mo ti kọ, mo ti kọ ọ́.

23 Nígbà náà ni àwọn ọmọ ogun, nígbà tí wọ́n kan Jésù mọ́ àgbélébùú tán, wọ́n mú aṣọ rẹ̀, wọ́n sì pín wọn sí ipa mẹ́rin, apákan fún ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan, àti ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀: ṣùgbọ́n ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ náà kò ní ojúrán, wọ́n hun ún láti òkè títí jáde.

24 Nítorí náà wọ́n wí fún ara wọn pé, “Ẹ má jẹ́ kí a fà á ya, ṣùgbọ́n kí a ṣẹ́ gègé nítorí rẹ̀.”Ti ẹni tí yóò jẹ́: kí ìwé-mímọ́ kí ó le ṣẹ, tí ó wí pé,“Wọ́n pín aṣọ mi láàárin ara wọn,wọ́n sì ṣẹ́ gègé fún aṣọ ìlekè mi.”Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn ọmọ ogun ṣe.

25 Ìyá Jésù àti arábìnrin ìyá rẹ̀ Màríà aya Kílópà, àti Màríà Magidalénì sì dúró níbi àgbélébùú,

26 Nígbà tí Jésù rí ìyá rẹ̀ àti ọmọ-ẹ̀yìn náà dúró, ẹni tí Jésù fẹ́ràn, ó wí fún ìyá rẹ̀ pé, “Obìnrin, wo ọmọ rẹ!”

27 Lẹ́yìn náà ni ó sì wí fún ọmọ-ẹ̀yìn náà pé, “Wo ìyá rẹ!” Láti wákàtí náà lọ ni ọmọ-ẹ̀yìn náà sì ti mú un lọ sí ilé ara rẹ̀.

Ikú Jésù

28 Lẹ́yìn èyí, bí Jésù ti mọ̀ pé, a ti parí ohun gbogbo tán, kí ìwé mímọ́ bà á lè ṣẹ, ó wí pé, “Òrùngbẹ ń gbẹ mí.”

29 Ohun èlò kan tí ó kún fún ọtí kíkan wà níbẹ̀, wọ́n tẹ kànrìnkàn bọ inú rẹ̀, wọ́n sì fi lé ori igi híssópù, wọ́n sì nà án sí i lẹ́nu.

30 Nígbà tí Jésù sì ti gba ọtí kíkan náà, ó wí pé, “Ó parí!” Ó sì tẹ orí rẹ̀ ba, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀.

31 Nítorí ó jẹ́ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́, kí òkú wọn má baà wà lórí àgbélébùú ní ọjọ́ ìsinmi, (nítorí ọjọ́ ńlá ni ọjọ́ ìsinmi náà) nítorí náà, àwọn Júù bẹ Pílátù pé kí a ṣẹ́ egungun itan wọn, kí a sì gbé wọn kúrò.

32 Nítorí náà, àwọn ọmọ ogun wá, wọ́n sì ṣẹ́ egungun itan ti èkínní, àti ti èkejì, tí a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀.

33 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jésù, tí wọ́n sì rí i pé ó ti kú, wọn kò ṣẹ́ egungun itan rẹ̀:

34 Ṣùgbọ́n ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ogun náà fi ọ̀kọ̀ gún un lẹ́gbẹ̀ẹ́, lójú kan náà, ẹ̀jẹ̀ àti omi sì tú jáde.

35 Ẹni tí ó rí sì jẹ́rìí, òtítọ́ sì ni ẹ̀rí rẹ̀: ó sì mọ̀ pé òótọ́ ni òun sọ, kí ẹ̀yin baà lè gbàgbọ́.

36 Nǹkan wọ̀nyí ṣe, kí ìwé mímọ́ ba à lè ṣẹ, tí ó wí pé, “A kì yóò fọ́ egungun rẹ̀.”

37 Ìwé mímọ́ mìíràn pẹ̀lú sì wí pé, “Wọn ó máa wo ẹni tí a gún lọ́kọ̀.”

Ìsìnkú Jésù

38 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ní Jóṣéfù ará Arimatíyà, ẹni tí ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn Jésù, ṣùgbọ́n ní ìkọ̀kọ̀, nítorí ìbẹ̀rù àwọn Júù, o bẹ Pílátù kí òun lè gbé òkú Jésù kúrò: Pílátù sì fún un ní àṣẹ. Nígbà náà ni ó wá, ó sì gbé òkú Jésù lọ.

39 Níkodémù pẹ̀lú sì wá, ẹni tí ó tọ Jésù wá lóru lákọ́kọ́, ó sì mú àdàpọ̀ òjíá àti álóè wá, ó tó ìwọ̀n ọgọ́rún lítà.

40 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé òkú Jésù, wọ́n sì fi aṣọ ọ̀gbọ̀ dì í pẹ̀lú tùràrí, gẹ́gẹ́ bí ìṣe àwọn Júù ti rí ní ìsìnkú wọn.

41 Àgbàlá kan sì wà níbi tí a gbé kàn án mọ́ àgbélébùú; ibojì titun kan sì wà nínú àgbàlá náà, nínú èyí tí a kò tíì tẹ́ ẹnìkan sí rí.

42 Ǹjẹ́ níbẹ̀ ni wọ́n sì tẹ́ Jésù sí, nítorí ìpalẹ̀mọ́ àwọn Júù; nítorí ibojì náà wà nítòòsí.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21