1 Ní àtètèkọ́ṣe ni Ọ̀rọ̀ wà, Ọ̀rọ̀ sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run, Ọlọ́run sì ni Ọ̀rọ̀ náà.
2 Òun ni ó sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run ní àtètèkọ́ṣe.
3 Nípaṣẹ̀ rẹ̀ ni a dá ohun gbogbo; lẹ́yìn rẹ̀ a kò sì dá ohun kan nínú ohun tí a ti dá.
4 Nínú rẹ̀ ni ìyè wà, ìyè yìí náà sì ni ìmọ́lẹ̀ aráyé,
5 Ìmọ́lẹ̀ náà sì ń mọ́lẹ̀ nínú òkùnkùn, òkùnkùn kò sì borí rẹ̀.
6 Ọkùnrin kan wà tí a rán láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá; orúkọ ẹni tí ń jẹ́ Jòhánù.
7 Òun ni a sì rán fún ẹ̀rí, kí ó lè ṣe ẹlẹ́rìí fún ìmọ́lẹ̀ náà, kí gbogbo ènìyàn kí ó lè gbàgbọ́ nípaṣẹ̀ rẹ̀.
8 Òun fúnrarẹ̀ kì í ṣe Ìmọ́lẹ̀ náà, ṣùgbọ́n a rán an wá láti ṣe ẹlẹ́rìí fún Ìmọlẹ̀ náà.
9 Ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ ń bẹ tí ń tan ìmọ́lẹ̀ fún olúkúlùkù ènìyàn tí ó wá sí ayé.
10 Òun sì wà ní ayé, àti pé, nípaṣẹ̀ rẹ̀ ni a sì ti dá ayé, ṣùgbọ́n ayé kò sì mọ̀ ọ́n.
11 Ó tọ àwọn tirẹ̀ wá, àwọn tirẹ̀ kò sì gbà á.
12 Ṣùgbọ́n iye àwọn tí ó gbà á, àní àwọn náà tí ó gbà orúkọ rẹ̀ gbọ́, àwọn ni ó fi agbára fún láti di ọmọ Ọlọ́run;
13 Àwọn ọmọ tí kì íṣe nípa ẹ̀jẹ̀, tàbí nípa ti ìfẹ́ ara, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nípa ìfẹ́ ti ènìyàn, bí kò ṣe láti ọwọ́ Ọlọ́run.
14 Ọ̀rọ̀ náà sì di ara, òun sì ń bá wa gbé. Àwa sì ti rí ògo rẹ̀, àní ògo Òun ọmọ bíbí kan ṣoṣo, àní Àyànfẹ́ rẹ̀ tí ó ti ọ̀dọ̀ Baba wá, ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ àti òtítọ́.
15 Jòhánù sì jẹ́rìí nípa rẹ̀, ó kígbe, ó sì wí pé, “Èyí ni ẹni tí mo sọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, ‘Ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn mi pọ̀ jù mí lọ, nítorí òun ti wà ṣáájú mi.’ ”
16 Nítorí láti inú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ ni gbogbo wa sì ti gba ìbùkún kún ìbùkún.
17 Nítorí pé nípaṣẹ̀ Mósè ni a ti fi òfin fún ni; oore-ọ̀fẹ́ àti òtítọ́ ti ipaṣẹ̀ Jésù Kírísítì wá.
18 Kò sí ẹni tí ó rí Ọlọ́run rí, ṣùgbọ́n Òun, àní Àyànfẹ́ rẹ̀ kan ṣoṣo, tí ń bẹ ní oókan àyà Baba, Òun náà ni ó fi í hàn.
19 Èyí sì ni ẹ̀rí Jòhánù, nígbà tí àwọn Júù rán àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì láti Jérúsálẹ́mù wá láti béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ ẹni tí òun ń ṣe.
20 Òun kò sì kùnà láti jẹ́wọ́, ṣùgbọ́n òun jẹ́wọ́ wọ́ọ́rọ́wọ́ pé, “Èmi kì í ṣe Kírísítì náà.”
21 Wọ́n sì bi í léèrè pé, “Ta há ni ìwọ? Èlíjà ni ìwọ bí?”Ó sì wí pé, “Èmi kọ́,”“Ìwọ ni wòlíì náà bí?”Ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́.”
22 Àṣẹ̀yìnwá àṣẹ̀yìnbọ̀ wọ́n wí fún un pé, “Ta ni ìwọ í ṣe? Fún wa ní ìdáhùn kí àwa kí ó lè mú èsì padà tọ àwọn tí ó rán wa wá lọ. Kí ni ìwọ wí nípa ti ara rẹ?”
23 Jòhánù sì fi ọ̀rọ̀ wòlíì Àìṣáyà fún wọn ní èsì pé, “Èmi ni ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù, ‘Ẹ ṣe ọ̀nà Olúwa ní títọ́.’ ”
24 Ọ̀kan nínú àwọn Farisí tí a rán
25 bi í léèrè pé, “Èéṣe tí ìwọ fí ń bamitíìsì nígbà náà, bí ìwọ kì í bá ṣe Kírísítì, tàbí Èlíjà, tàbí wòlíì náà?”
26 Jòhánù dá wọn lóhùn, wí pé, “Èmi ń fi omi ṣe ìtẹ̀bọmi: ẹnìkan dúró láàárin yín, ẹni tí ẹ̀yin kò mọ̀;
27 Òun náà ni ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn mi, okùn bàtà ẹni tí èmi kò tó láti tú.”
28 Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó ṣẹlẹ̀ ní Bétanì ní òdì kejì odò Jọ́dánì, níbi tí Jòhánù ti ń ṣe ìtẹ̀bọmi.
29 Ní ọjọ́ kejì Jòhánù rí Jésù tí ó ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Wò ó, Ọ̀dọ́-àgùntàn Ọlọ́run, ẹni tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ!
30 Èyí ni ẹni tí mo ń sọ nígbà tí mo wí pé, ‘Ọkùnrin kan tí ń bọ̀ wá lẹ́yìn mi pọ̀ jù mí lọ nítorí tí ó ti wà ṣáájú mi.’
31 Èmi gan-an kò sì mọ̀ ọ́n, ṣùgbọ́n ìdí tí mo fi wá ń fi omi ṣe ìtẹ̀bọmi ni kí a lè fi í hàn fún Ísírẹ́lì.”
32 Nígbà náà ni Jòhánù jẹ́rìí sí i pé: “Mo rí Ẹ̀mi sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá bí àdàbà, tí ó sì bà lé e.
33 Èmí kì bá tí mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe pé ẹni tí ó rán mi láti fi omi bamitíìsì sọ fún mi pé, ‘Ọkùnrin tí ìwọ rí tí Ẹ̀mí sọ̀kalẹ̀ tí ó bà lé lórí ni ẹni tí yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ bamitíìsì.’
34 Èmi ti rí i, mo sì jẹ́rìí pé, èyí ni Ọmọ Ọlọ́run.”
35 Ní ọjọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Jòhánù dúró, pẹ̀lú méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.
36 Nígbà tí ó sì rí Jésù bí ó ti ń kọjá lọ, ó wí pé, “Wò ó Ọ̀dọ́-àgùntàn Ọlọ́run!”
37 Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì náà sì gbọ́ ohun tí ó wí yìí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sì í tọ Jésù lẹ́yìn.
38 Nígbà náà ni Jésù yípadà, ó rí i pé wọ́n ń tọ Òun lẹ́yìn, ó sì béèrè pé, “Kí ni ẹ̀yin ń wá?”Wọ́n wí fún un pé, “Rábì” (ìtumọ̀ èyí tí í ṣe Olùkọ́ni), “Níbo ni ìwọ ń gbé?”
39 Ó wí fún wọn pé, “Ẹ wá wò ó, ẹ̀yin yóò sì rí i.”Wọ́n sì wá, wọ́n sì rí ibi tí ó ń gbé, wọ́n sì wà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ náà. Ó jẹ́ ìwọ̀n wákàtí kẹwàá ọjọ́.
40 Ańdérù, arákùnrin Símónì Pétérù, jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn méjì tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Jòhánù, tí ó sì tọ Jésù lẹ́yìn.
41 Ohun àkọ́kọ́ tí Ańdérù ṣe ni láti wá Símónì arákùnrin rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Àwa ti rí Mèṣáyà” (ẹni tí ṣe Kírísítì).
42 Ó sì mú un wá sọ́dọ̀ Jésù.Jésù sì wò ó, ó wí pé, “Ìwọ ni Símónì ọmọ Jónà: Kéfà ni a ó sì máa pè ọ” (ìtumọ̀ èyí tí ṣe Pétérù).
43 Ní ọjọ́ kéjì Jésù ń fẹ́ jáde lọ sí Gálílì, ó sì rí Fílípì, ó sì wí fún un pé, “Má a tọ̀ mí lẹ́yìn.”
44 Fílípì gẹ́gẹ́ bí i Ańdérù àti Pétérù, jẹ́ ará ìlú Bẹtiṣáídà.
45 Fílípì rí Nàtaníẹ́lì, ó sì wí fún un pé, “Àwa ti rí ẹni náà tí Mósè kọ nípa rẹ̀ nínú òfin àti ẹni tí àwọn wòlíì ti kọ̀wé rẹ̀—Jésù ti Násárẹ́tì, ọmọ Jósẹ́fù.”
46 Nàtaníẹ́lì béèrè pé, “Násárẹ́tì? Ohun rere kan há lè ti ibẹ̀ jáde?”Fílípì wí fún un pé, “Wá wò ó.”
47 Jésù rí Nàtaníẹ́lì ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí nípa rẹ̀ pé, “Èyí ni ọmọ Ísírẹ́lì tòótọ́, nínú ẹni tí ẹ̀tàn kò sí.”
48 Nàtaníẹ́lì béèrè pé, “Báwo ni ìwọ ti ṣe mọ̀ mí?”Jésù sì dáhùn pé, “Èmi rí ọ nígbà tí ìwọ wà lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ kí Fílípì tó pè ọ́.”
49 Nígbà náà ni Nàtaníẹ́lì sọ ọ́ gbangba pé, “Rábì, Ìwọ ni ọmọ Ọlọ́run; Ìwọ ni Ọba Ísírẹ́lì.”
50 Jésù sì wí fún un pé, “Ìwọ gbàgbọ́ nítorí mo wí fún ọ pé mo rí ọ lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́. Ìwọ ó rí ohun tí ó pọ̀ jù ìwọ̀nyí lọ.”
51 Nígbà náà ni ó fi kún un pé, “Èmi wí fún yín nítòótọ́, ẹ̀yin yóò rí ọ̀run ṣí sílẹ̀, àwọn ańgẹ́lì Ọlọ́run yóò sì máa gòkè, wọ́n ó sì máa sọ̀kalẹ̀ sórí Ọmọ Ènìyàn.”