Jòhánù 3 BMY

Jésù Kọ́ Nikodémù

1 Ọkùnrin kan sì wà nínú àwọn Farisí, tí a ń pè ní Níkódémù, ìjòyè kan láàrin àwọn Júù:

2 Òun náà ní ó tọ Jésù wá ní òru, ó sì wí fún un pé, Rábì, àwa mọ̀ pé olùkọ́ni láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ni ìwọ ń ṣe: nítorí pé kò sí ẹni tí ó lè ṣe iṣẹ́ àmì wọ̀nyí tí ìwọ ń ṣe, bí kò se pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀.

3 Jésù dáhùn ó sì wí fún un pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, bí kò ṣe pé a tún ènìyàn bí, òun kò lè rí ìjọba Ọlọ́run.”

4 Nikodémù wí fún un pé, a ó ti ṣe lè tún ènìyàn bí nígbà tí ó di àgbàlagbà tan? Ó ha lè wọ inú ìyá rẹ̀ lọ nígbà kejì, kí a sì bí i?

5 Jésù dáhùn wí pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, bí kò ṣe pé a fi omi àti Ẹ̀mí bí ènìyàn, òun kò lè wọ ìjọba Ọlọ́run.

6 Èyí tí a bí nípa ti ara, ti ara ni; èyí tí a sì bí nípa ti Ẹ̀mí, ti ẹ̀mí ni.

7 Kí ẹnu kí ó má ṣe yà ọ́, nítorí mo wí fún ọ pé, ‘A kò lè ṣe aláìtún yín bí.’

8 Afẹ́fẹ́ ń fẹ́ sí bi tí ó gbé wù ú, ìwọ sì ń gbọ́ ìró rẹ̀, ṣùgbọ́n ìwọ kò mọ ibi tí ó gbé ti wá, àti ibi tí ó gbé ń lọ: gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ẹni tí a bí nípa ti Ẹ̀mí.”

9 Nikodémù dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Nǹkan wọ̀nyí yóò ti ṣe lè rí bẹ́ẹ̀?”

10 Jésù dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Ṣé olùkọ́ni ní Ísírẹ́lì ni ìwọ ń ṣe, o kò sì mọ nǹkan wọ̀nyí?

11 Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, Àwa ń sọ èyí tí àwa mọ̀, a sì ń jẹ́rìí èyí tí àwa ti rí; ẹ̀yin kò sì gba ẹ̀rí wa.

12 Bí mo bá sọ ohun ti ayé yìí fún yín, tí ẹ̀yin kò sì gbàgbọ́, ẹ̀yin ó ti ṣe gbàgbọ́ bí mo bá sọ ohun ti ọ̀run fún yín?

13 Kò sì sí ẹni tí ó gòkè re ọ̀run bí kò ṣe ẹni tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, Ọmọ Ènìyàn tí ń bẹ ní ọ̀run.

14 Bí Móse sì ti gbé ejò sókè ní ihà, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni a kò le ṣe aláìgbé Ọmọ-Ènìyàn sókè pẹ̀lú:

15 Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́, kí ó má bà á ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó le ní iyè àìnípẹ̀kun.

16 “Nítorí Ọlọ́run fẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, tí ó fi ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́, má bà á ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní iyè àìnípẹ̀kun.

17 Nítorí Ọlọ́run kò rán ọmọ rẹ̀ sí ayé láti dá aráyé lẹ́jọ́; ṣùgbọ́n kí a le ti ipaṣẹ̀ rẹ̀ gba aráyé là.

18 Ẹni tí ó bá gbà á gbọ́, a kò ní dá a lẹ́jọ́; ṣùgbọ́n a ti dá ẹni tí kò gbà á gbọ́ lẹ́jọ́ ná, nítorí tí kò gba orúkọ ọmọ bíbí kan ṣoṣo ti Ọlọ́run gbọ́.

19 Èyí ni ìdájọ́ náà pé, ìmọ́lẹ̀ wá sí ayé, àwọn ènìyàn sì fẹ́ òkùnkùn ju ìmọ́lẹ̀ lọ, nítorí tí iṣẹ́ wọn burú.

20 Nítorí olúkúlùkù ẹni tí ó bá hùwà búburú níí ìkórìíra ìmọ́lẹ̀, kìí sí wá sí ìmọ́lẹ̀, kí a má ṣe bá iṣẹ́ rẹ̀ wí.

21 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń sọ òtítọ́ níí wá sí ìmọ́lẹ̀, kí iṣẹ́ rẹ̀ kí ó lè fi ara hàn pé a ṣe wọ́n nípa ti Ọlọ́run.”

Ẹ̀rí Jòhánù Nípa Jésù

22 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jésù pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá sí ilẹ̀ Jùdíà; ó sì dúró pẹ̀lú wọn níbẹ̀ ó sì ń ṣe ìtẹ̀bọmi fún ni.

23 Jòhánù pẹ̀lú sì ń ṣe ìtẹ̀bọmi ní Áhínónì, ní agbégbé Sálímù, nítorí tí omi púpọ̀ wà níbẹ̀: wọ́n sì ń wá, a sì ń tẹ̀ ẹ́ wọn bọmi.

24 Nítorí tí a kò tí ì sọ Jòhánù sínú túbú.

25 Nígbà náà ni iyàn kan wà láàárin àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jòhánù, àti Júù kan nípa ti ìwẹ̀nù.

26 Wọ́n sì tọ Jòhánù wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Rábì, ẹni tí ó ti wà pẹ̀lú rẹ lókè odò Jọ́dánì, tí ìwọ ti jẹ́rí rẹ̀, wò ó, òun tẹ ni bọmi, gbogbo ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ wá.”

27 Jòhánù dáhùn ó sì wí pé, “Ènìyàn kò le rí ǹkankan gbà, bí kò ṣepé a bá ti fi fún ún láti ọ̀run wá.

28 Èyin fúnra yín jẹ́rìí mi, pé mo wí pé, ‘Èmi kì í ṣe Kírísítì náà, ṣùgbọ́n pé a rán mi ṣíwájú rẹ̀.’

29 Ẹni tí ó bá ni ìyàwó ni ọkọ ìyàwó; ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó tí ó dúró tí ó sì ń gbóhùn rẹ̀, ó ń yọ̀ gidigidi nítorí ohùn ọkọ ìyàwó; nítorí náà ayọ̀ mi yí di kíkún.

30 Òun kò lè ṣàì máa pọ̀ sí i, ṣùgbọ́n èmi kò lè ṣàì má relẹ̀.

31 “Ẹni tí ó ti òkè wá ju gbogbo ènìyàn lọ; ẹni tí ó ti ayé wá ti ayé ni, a sì máa sọ ohun ti ayé. Ẹni tí ó ti ọ̀run wá ju gbogbo ènìyàn lọ.

32 Ohun tí ó ti rí tí ó sì ti gbọ́ èyí náà sì ni òun ń jẹ́rìí rẹ̀; kò sì sí ẹni tí ó gba ẹ̀rí rẹ̀.

33 Ẹni tí ó gba ẹ̀rí rẹ̀ fi èdìdì dì í pé, olótìítọ́ ni Ọlọ́run.

34 Nítorí ẹni tí Ọlọ́run ti rán ń sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: nítorí tí Ọlọ́run fi Ẹ̀mí fún un láìsí gbèdéke.

35 Baba fẹ́ Ọmọ, ó sì ti fi ohun gbogbo lé e lọ́wọ́

36 Ẹni tí ó bá gba Ọmọ gbọ́, ó ní ìyè àìnípẹ̀kun: ẹni tí kò bá sì gba Ọmọ gbọ́, kì yóò rí ìyè; nítorí ìbínú Ọlọ́run ń bẹ lórí rẹ̀.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21