Jòhánù 20 BMY

Òfo Ibojì

1 Ní ọjọ́ kínní ọ̀ṣẹ̀ kùtùkùtù nígbà tí ilẹ̀ kò tíì mọ́ ni Màríà Magídalénè wá sí ibojì, ó sì rí i pé, a ti gbé òkúta kúrò lẹ́nu ibojì.

2 Nítorí náà, ó sáré, ó sì tọ Símónì Pétérù wá, àti ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn náà ẹni tí Jésù fẹ́ràn, ó sì wí fún wọn pé, “Wọ́n ti gbé Olúwa kúrò nínú ibojì, àwa kò sì mọ ibi tí wọ́n gbé tẹ́ ẹ sí.”

3 Nígbà náà ni Pétérù jáde, àti ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn náà, wọ́n sì wá sí ibojì.

4 Àwọn méjèèjì sì jùmọ̀ sáré: èyí ọmọ-ẹ̀yìn sì sáré ya Pétérù, ó sì kọ́kọ́ dé ibojì.

5 Ó sì bẹ̀rẹ̀ láti wo inú rẹ̀, ó rí aṣọ ọ̀gbọ̀ náà ní ilẹ̀; ṣùgbọ́n òun kò wọ inú rẹ̀.

6 Nígbà náà ni Símónì Pétérù tí ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀ dé, ó sì wọ inú ibojì, ó sì rí aṣọ ọ̀gbọ̀ náà ní ilẹ̀.

7 Àti pé, gèlè tí ó wà níbi orí rẹ̀ kò sì wà pẹ̀lú aṣọ ọ̀gbọ̀ náà, ṣùgbọ́n o ká jọ ní ibìkan fúnra rẹ̀.

8 Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn náà, ẹni tí ó kọ́ dé ibojì wọ inú rẹ̀ pẹ̀lú, ó sì rí i ó sì gbàgbọ́.

9 (Nítorí tí wọn kò sáà tí mọ ìwé mímọ́ pé, òun ní láti jíǹde kúrò nínú òkú.)

Jésù Fi Ara Han Màríà Mágidalénì

10 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà sì tún padà lọ sí ilé wọn.

11 Ṣùgbọ́n Màríà dúró létí ibojì lóde, ó ń sọkún: bí ó ti ń ṣọkún, bẹ́ẹ̀ ni ó bẹ̀rẹ̀, ó sì wo inú ibojì.

12 Ó sì kíyèsí àwọn áńgẹ́lì méjì aláṣọ funfun, wọ́n jókòó, ọ̀kan níhà orí àti ọ̀kan níhà ẹsẹ̀, níbi tí òkú Jésù gbé ti sùn sí.

13 Wọ́n sì wí fún un pé, “Obìnrin yìí, èé ṣe tí ìwọ fi ń sọkún?”Ó sì wí fún wọn pé, “Nítorí tí wọ́n ti gbé Olúwa mi, èmi kò sì mọ ibi tí wọ́n gbé tẹ́ ẹ sí.”

14 Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó yípadà, ó sì rí Jésù dúró, kò sì mọ̀ pé Jésù ni.

15 Jésù wí fún un pé, “Obìnrin yìí, èé ṣe tí ìwọ fi ń sọkún? Ta ni ìwọ ń wá?”Òun ṣebí olùsọ́gbà ní í ṣe, ó wí fún un pé, “Alàgbà, bí ìwọ bá ti gbé e kúrò níhìn yìí, sọ ibi tí o tẹ́ ẹ sí fún mi, èmi ó sì gbé e kúrò.”

16 Jésù wí fún un pé, “Màríà!”Ó sì yípadà, ó wí fún un pé, “Rábónì!” (èyí tí ó jẹ́ Olùkọ́)

17 Jésù wí fún un pé, “Má ṣe fi ọwọ́ kàn mí; nítorí tí èmi kò tíì gókè lọ sọ́dọ̀ Baba mi: ṣùgbọ́n, lọ sọ́dọ̀ àwọn arákùnrin mi, sì wí fún wọn pé, ‘Èmi ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Baba mi, àti Baba yín: àti sọ́dọ̀ Ọlọ́run mi, àti Ọlọ́run yín.’ ”

18 Màríà Magídalénè wá, ó sì sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, “Òun ti rí Olúwa!” Àti pé, ó sì ti fi nǹkan wọ̀nyí fún òun.

Jésù Fi Ara Han Àwọn Àpósítélì

19 Lọ́jọ́ kan náà, lọ́jọ́ kínní ọ̀ṣẹ̀ nígbà tí alẹ́ lẹ́, tí a sì ti ìlẹ̀kùn ibi tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn gbé péjọ, nítorí ìbẹ̀rù àwọn Júù, bẹ́ẹ̀ ni Jésù dé, ó dúró láàárin, ó sì wí fún wọn pé, “Àlàáfíà fún yín.”

20 Nígbà tí ó sì ti wí bẹ́ẹ̀ tán, ó fi ọwọ́ àti ìhà rẹ̀ hàn wọ́n. Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn yọ̀, nígbà tí wọ́n rí Olúwa.

21 Nítorí náà, Jésù sì tún wí fún wọn pé, “Àlàáfíà fún yín: gẹ́gẹ́ bí Baba ti rán mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi sì rán yín.”

22 Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó mí sí wọn, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ gba Ẹ̀mí mímọ́!

23 Ẹ̀ṣẹ̀ ẹnikẹ́ni tí ẹ̀yin bá fi jì, a fi jì wọ́n; ẹ̀ṣẹ̀ ẹnikẹ́ni tí ẹ̀yin bá dá dúró, a dá wọn dúró.”

Jésù Fi Ara Han Tọ́másì

24 Ṣùgbọ́n Tómásì, ọ̀kan nínú àwọn méjìlá, tí a ń pè ní Dídímù, kò wà pẹ̀lú wọn nígbà tí Jésù dé.

25 Nítorí náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ìyókù wí fún un pé, “Àwa ti rí Olúwa!”Ṣùgbọ́n ó wí fún un pé, “Bí kò ṣe pé mo bá rí àpá ìṣó ni ọwọ́ rẹ̀ kí èmi sì fi ìka mi sí àpá ìṣó náà, kí èmi sì fi ọwọ́ mi sí ìhà rẹ̀, èmi kì yóò gbàgbọ́!”

26 Lẹ́yìn ijọ́ mẹ́jọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì tún wà nínú ilé, àti Tọ́másì pẹ̀lú wọn: nígbà tí a sì ti ti ìlèkùn, Jésù dé, ó sì dúró láàrin, ó wí pé, “Àlàáfíà fún yín.”

27 Nígbà náà ni ó wí fún Tọ́másì pé, “Mú ìka rẹ wá níhín yìí, kí o sì wo ọwọ́ mi; sì mú ọwọ́ rẹ wá níhín, kí o sì fi sí ìhà mi: kí ìwọ má ṣe jẹ́ aláìgbàgbọ́ mọ́, ṣùgbọ́n jẹ́ onígbàgbọ́.”

28 Tọ́másì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Olúwa mi àti Ọlọ́run mi!”

29 Jésù wí fún un pé, “Nítorí tí ìwọ rí mi ni ìwọ ṣe gbàgbọ́: alábùkún fún ni àwọn tí kò rí mi, tí wọ́n sì gbàgbọ́!”

30 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àmì mìíràn ni Jésù ṣe níwájú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, tí a kò kọ sínú ìwé yìí:

31 Ṣùgbọ́n wọ̀nyí ni a kọ, kí ẹ̀yin lè gbàgbọ́ pé Jésù ní í ṣe Kírísítì náà, Ọmọ Ọlọ́run, àti pé gbígbàgbọ́, kí ẹ̀yin lè ní ìyè ní orúkọ rẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21