Jòhánù 16 BMY

1 “Nǹkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín, kí a má baà mú yín kọsẹ̀.

2 Wọ́n ó yọ yín kúrò nínú Sínágógù: àní, àkókò ń bọ̀, tí ẹnikẹ́ni tí ó bá pa yín, yóò rò pé òun ń ṣe ìsìn fún Ọlọ́run.

3 Nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n ó sì ṣe, nítorí tí wọn kò mọ Baba, wọn kò sì mọ̀ mí.

4 Ṣùgbọ́n nǹkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín, pé nígbà tí wákàtí wọn bá dé, kí ẹ lè rántí wọn pé mo ti wí fún yín. Ṣùgbọ́n èmi kò sọ nǹkan wọ̀nyí fún yín láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ wá, nítorí tí mo wà pẹ̀lú yín.

Iṣẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́

5 “Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí èmi ń lọ sọ́dọ̀ ẹni tí ó rán mi; kò sì sí ẹnìkan nínú yín tí ó bi mí lérè pé, ‘Níbo ni ìwọ ń lọ?’

6 Ṣùgbọ́n nítorí mo sọ nǹkan wọ̀nyí fún yín, ìbìnújẹ́ kún ọkàn yín.

7 Ṣùgbọ́n òtítọ́ ni èmi ńsọ fún yín; àǹfàní ni yóò jẹ́ fún yín bí èmi bá lọ: nítorí bí èmi kò bá lọ, Olùtùnú kì yóò tọ̀ yín wá; ṣùgbọ́n bí mo bá lọ, èmi ó rán an sí yín.

8 Nígbà tí òun bá sì dé, yóò fi òye yé aráíyé níti ẹ̀ṣẹ̀, àti ní ti òdodo, àti níti ìdájọ́:

9 Ní ti ẹ̀ṣẹ, nítorí tí wọn kò gbà mí gbọ́;

10 Ní ti òdodo, nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba, ẹ̀yin kò sì mọ̀ mí;

11 Ní ti ìdájọ́, nítorí tí a ti ṣe ìdájọ́ aládé ayé yìí.

12 “Mo ní ohun pípọ̀ láti sọ fún yín pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ẹ kò lè gbà wọ́n nísinsìn yìí.

13 Ṣùgbọ́n nígbà tí òun, àní Ẹ̀mí òtítọ́ náà bá dé, yóò tọ́ yín sí ọ̀nà òtítọ́ gbogbo; nítorí kì yóò sọ ti ara rẹ̀; ṣùgbọ́n ohunkóhun tí ó bá gbọ́, òun ni yóò máa sọ: yóò sì sọ ohun tí ń bọ̀ fún yín.

14 Òun ó máa yìn mí lógo: nítorí tí yóò gbà nínú ti èmi, yóò sì máa sọ ọ́ fún yín.

15 Ohun gbogbo tí Baba ní tèmi ni: nítorí èyí ni mo ṣe wí pé, òun ó gba nínú tèmi, yóò sì sọ ọ́ fún yín.

16 “Nígbà díẹ̀, ẹ̀yin kì ó sì rí mi: àti nígbà díẹ̀ ẹ̀wẹ̀, ẹ ó sì rí mi, nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba.”

Ìbànújẹ́ Àwọn Ọmọ-Ẹ̀yìn Yóò Di Ayọ̀

17 Nítorí náà òmíràn nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń bá ara wọn sọ pé, “Kí ni èyí tí o wí fún wa yìí, nígbà díẹ̀, ẹ̀yin ó sì rí mi: àti nígbà díẹ̀ ẹ̀wẹ̀, ẹ̀yin kì yóò rí mi: àti, nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba?”

18 Nítorí náà wọ́n wí pé, kí ni èyí tí ó wí yí, nígbà díẹ̀? Àwa kò mọ̀ ohun tí ó wí.

19 Jésù sáà ti mọ̀ pé, wọ́n ń fẹ́ láti bi òun léèrè, ó sì wí fún wọn pé, ẹ̀yin ń bi ara yín léèrè ní ti èyí tí mo wí pé, nígbà díẹ̀, ẹ̀yin kì ó sì rí mi: àti nígbà díẹ̀ ẹ̀wẹ̀, ẹ̀yin ó sì rí mi?

20 Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé, ẹ̀yin ó máa sọkún ẹ ó sì máa pohùnréré ẹkún, ṣùgbọ́n àwọn aráyé yóò máa yọ̀: inú yín yóò sì di ayọ̀.

21 Nígbà tí obìnrin bá ń rọbí, a ní ìbìnújẹ́, nítorí tí wákàtí rẹ̀ dé: ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá ti rí ọmọ náà tán, òun kì í sì í rántí ìrora náà mọ́, fún ayọ̀ nítorí a bí ènìyàn sí ayé.

22 Nítorí náà ẹ̀yin ní ìbànújẹ́ nísinsìn yìí: ṣùgbọ́n èmi ó tún rí yín, ọkàn yín yóò sì yọ̀, kò sì sí ẹni tí yóò gba ayọ̀ yín lọ́wọ́ yín.

23 Àti ní ijọ́ náà ẹ̀yin kì ó bi mí lérè ohunkóhun. Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ohunkóhun tí ẹ̀yin bá bèèrè lọ́wọ́ Baba ní orúkọ mi, òhun ó fi fún yín.

24 Títí di ìsinyìí ẹ kò tíì bèèrè ohunkóhun ní orúkọ mi: ẹ bèèrè, ẹ ó sì rí gbà, kí ayọ̀ yín kí ó lè kún.

25 “Nǹkan wọ̀nyí ni mo fi òwe sọ fún yín: ṣùgbọ́n àkókò dé, nígbà tí èmi kì yóò fi òwe bá yín sọ̀rọ̀ mọ́, ṣùgbọ́n èmi ó sọ ti Baba fún yín gbangba.

26 Ní ọjọ́ náà, ẹ̀yin ó béèrè ní orúkọ mi: èmi kò sì wí fún yín pé, èmi ó bèèrè lọ́wọ́ Baba fún yín:

27 Nítorí tí Baba tìkara rẹ̀ fẹ́ràn yín, nítorí tí ẹ̀yin ti fẹ́ràn mi, ẹ sì ti gbàgbọ́ pé, lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni èmi ti jáde wá.

28 Mo ti ọ̀dọ̀ Baba jáde wá, mo sì wá sí ayé: ẹ̀wẹ̀, mo fi ayé sílẹ̀, mo sì lọ sọ́dọ̀ Baba.”

29 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Wò ó, nígbà yìí ni ìwọ ń sọ̀rọ̀ gbangba, ìwọ kò sì sọ ohunkóhun ní òwe.

30 Nígbà yìí ni àwa mọ̀ pé, ìwọ mọ̀ ohun gbogbo, ìwọ kò ní kí a bi ọ́ léèrè: nípa èyí ni àwa gbàgbọ́ pé, lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni ìwọ ti jáde wá.”

31 Jésù dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin gbàgbọ́ wàyí?

32 Kíyèsí i, wákàtí ń bọ̀, àní ó dé tan nísinsin yìí, tí a ó fọ́n yín ká kiri, olúkúlùkù sí ilé rẹ̀; ẹ ó sì fi èmi nìkan sílẹ̀: ṣùgbọ́n kì yóò sì ṣe èmi nìkan, nítorí tí Baba ń bẹ pẹ̀lú mi.

33 “Nǹkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín tẹ́lẹ̀, kí ẹ̀yin kí ó lè ní àlàáfíà nínú mi. Nínú ayé, ẹ̀yin ó ní ìpọ́njú; ṣùgbọ́n ẹ tújúká; mo ti ṣẹ́gun ayé.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21