Jòhánù 12 BMY

Ìfàmì-Òróró Yàn Jésù Ni Bẹ́tanì

1 Nítorí náà, nígbà tí àjọ ìrékọjá ku ìjọ́ mẹ́fà, Jésù wá sí Bẹ́tanì, níbi tí Lásárù wà, ẹni tí ó ti kú, tí Jésù jí dìde kúrò nínú òkú.

2 Wọ́n sì se àṣè alẹ́ fún un níbẹ̀: Màtá sì ń ṣe ìránṣẹ́: ṣùgbọ́n Lásárù Jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí ó jókòó níbi tábìlì rẹ̀.

3 Nígbà náà, Màtá mú òróró ìkunra nádì, òṣùwọ̀n lítà kan, àìlábùlà, olówó iyebíye, ó sì ń fi kun Jésù ní ẹṣẹ̀, ó sì ń fi irun orí rẹ̀ nu ẹṣẹ̀ rẹ̀ nù: ilẹ̀ sì kún fún òórùn ìkunra náà.

4 Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Júdásì Isíkáríótù, ọmọ Símónì ẹni tí yóò fi í hàn, wí pé,

5 “Èé ṣe tí a kò ta òróró ìkunra yìí ní ọ̀ọ́dúnrún owó idẹ kí a sì fi fún àwọn talákà?”

6 Ṣùgbọ́n ó wí èyí, kì í ṣe nítorí tí ó náání àwọn talákà; ṣùgbọ́n nítorí tí ó jẹ́ olè, òun ni ó sì ní àpò, a sì máa gbé ohun tí a fi sínú rẹ̀.

7 Nígbà náà ni Jésù wí pé, “Ẹ fi í sílẹ̀, ó ṣe é sílẹ̀ de ọjọ́ ìsìnkú mi.

8 Nígbà gbogbo ni ẹ̀yin sáà ní talákà pẹ̀lú yín; ṣùgbọ́n èmi ni ẹ kò ní nígbà gbogbo.”

9 Nítorí náà, ìjọ ènìyàn nínú àwọn Júù ni ó mọ̀ pé ó wà níbẹ̀; wọ́n sì wá, kì í ṣe nítorí Jésù nìkan, ṣùgbọ́n kí wọn lè rí Lásárù pẹ̀lú, ẹni tí ó ti jí dìde kúrò nínú òkú.

10 Ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà gbìmọ̀ kí wọn lè pa Lásárù pẹ̀lú;

11 Nítòrí pé nípasẹ̀ rẹ̀ ni ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù jáde lọ, wọ́n sì gbà Jésù gbọ́.

Jésù Gun Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Wọ Jérúsálẹ́mù

12 Ní ijọ kejì nígbà tí ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó wá sí àjọ gbọ́ pé, Jésù ń bọ̀ wá sí Jérúsálẹ́mù.

13 Wọ́n mú imọ̀ ọ̀pẹ, wọ́n sì jáde lọ pàdé rẹ̀, wọ́n sì ń kígbe pé,“Hòsánnà!”“Olùbùkún ni ẹni tí ń bọ̀wá ní orúkọ Olúwa, ọba Ísríẹ́lì!”

14 Nígbà tí Jésù sì rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan, ógùn ún; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé pé,

15 “Má bẹ̀rù, ọmọbìnrin Síónì;Wò ó, ọba rẹ ń bọ̀ wá,Ó jókòó lórí ọmọ kẹ́tẹ́ktẹ́.”

16 Nǹkan wọ̀nyí kò tètè yé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀: ṣùgbọ́n nígbà tí a ṣe Jésù lógo, nígbà náà ni wọ́n rántí pé, a kọ̀wé ǹkan wọ̀nyí nípa rẹ̀ sí i.

17 Nítorí náà, ìjọ ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tí wọ́n gbọ́ pé Lásárù jáde nínú ibojì rẹ̀, tí ó sì jí i dìde kúrò nínú òkú, jẹ́rí sí i.

18 Nítorí èyí ni ìjọ ènìyàn sì ṣe lọ pàdé rẹ̀, nítorí tí wọ́n gbọ́ pé ó ti ṣe iṣẹ́ àmì yìí.

19 Nítorí náà àwọn Farisí wí fún ara wọn pé, “Ẹ kíyèsi bí ẹ kò ti lè borí ní ohunkóhun? Ẹ wo bí gbogbo ayé ti ń wọ́ tọ̀ ọ́!”

Jésù Sọ Nípa Ikú Rẹ̀

20 Àwọn Gíríkì kan sì wà nínú àwọn tí ó gòkè wá láti sìn nígbà àjọ:

21 Àwọn wọ̀nyí ni ó tọ Fílípì wá, ẹni tí í ṣe ará Bẹtisáídà tí Gálílì, wọ́n sì ń bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀, pé, “Alàgbà, àwa ń fẹ́ rí Jésù!”

22 Fílípì wá, ó sì sọ fún Ańdérù; Ańdérù àti Fílípì wá, wọ́n sì sọ fún Jésù.

23 Jésù sì dá wọn lóhùn pé, “Wákàtí náà dé, tí a ó ṣe Ọmọ ènìyàn lógo.

24 Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, bí kò ṣe pé àlìkámà bá bọ́ sí ilẹ̀, tí ó bá sì kú, ó wà ní òun nìkan; ṣùgbọ́n bí ó bá kú, a sì so ọ̀pọ̀lọpọ̀ èso.

25 Ẹni tí ó bá fẹ́ ẹ̀mí rẹ̀ yóò sọ ọ́ nù; ẹni tí ó bá sì kórìíra ẹ̀mí rẹ̀ láyé yìí ni yóò sì pa á mọ́ títí ó fi di ìyè àìnípẹ̀kun.

26 Bí ẹnikẹ́ni bá ń sìn mí, kí ó máa tọ̀ mí lẹ́yìn: àti níbi tí èmi bá wà, níbẹ̀ ni ìránṣẹ́ mi yóò wà pẹ̀lú: bí ẹnikẹ́ni bá ń sìn mí, òun ni Baba yóò bu ọlá fún.

27 “Ní ìsinsin yìí ni a ń pọ́n ọkàn mi lójú; kínni èmi ó sì wí? ‘Baba, gbà mí kúrò nínú wákàtí yìí’? Rárá, ṣùgbọ́n nítorí èyì ni mo ṣe wá sí wákàtí yìí.

28 Baba, ṣe orúkọ rẹ lógo!”Nígbà náà ni ohùn kan ti ọ̀run wá, wí pé, “Èmi ti ṣe é lógo!”

29 Nítorí náà ìjọ ènìyàn tí ó dúró níbẹ̀, tí wọ́n sì gbọ́ ọ, wí pé, àrá ń sán: àwọn ẹlòmíràn wí pé, “Ańgẹ́lì kan ni ó ń bá a sọ̀rọ̀.”

30 Jésù sì dáhùn wí pé, “Kì í ṣe nítorí mi ni ohùn yìí ṣe wá, bí kò ṣe nítorí yín.

31 Ní ìsinsin yìí ni ìdájọ́ ayé yìí dé: nísinsin yìí ni a ó lé aládé ayé yìí jáde.

32 Àti èmi, bí a bá gbé mi sókè èmi ó fa gbogbo ènìyàn sọ́dọ̀ ara mi!”

33 Ṣùgbọ́n ó wí èyí, ó ń ṣàpẹrẹ irú ikú tí òun ó kú.

34 Nítorí náà àwọn ìjọ ènìyàn dá a lóhùn pé, “Àwa gbọ́ nínú òfin pé, Kírísítì wà títí láéláé: ìwọ ha ṣe wí pé, ‘A ó gbé ọmọ ènìyàn sókè? Ta ni ó ń jẹ́ ọmọ ènìyàn yìí’?”

35 Nígbà náà ni Jésù wí fún wọn pé, “Nígbà díẹ̀ sí i ni ìmọ́lẹ̀ wà láàárin yín, ẹ máa rìn nígbà tí ẹ̀yin ní ìmọ́lẹ̀, kí òkùnkùn má ṣe bá yín: ẹni tí ó bá sì ń rìn ní òkùnkùn kò mọ ibi òun gbé ń lọ.

36 Nígbà tí ẹ̀yin ní ìmọ́lẹ̀, ẹ gba ìmọ́lẹ̀ gbọ́, kí ẹ lè jẹ́ ọmọ ìmọ́lẹ̀!” Nǹkan wọ̀nyí ni Jésù sọ, ó sì jáde lọ, ó fi ara pamọ́ fún wọn.

Àwọn Júù Ń Tẹ̀síwájú Nínú Àìgbàgbọ́

37 Ṣùgbọ́n bí ó ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àmì tó báyìí lójú wọn, wọn kò gbà á gbọ́.

38 Kí ọ̀rọ̀ wòlíì Ìsàíàh lè ṣẹ, èyí tí ó sọ pé:“Olúwa, tani ó gba ìwàásù wa gbọ́Àti ta ni a sì fi apá Olúwa hàn fún?”

39 Nítorí èyí ni wọn kò fi lè gbàgbọ́, nítorí Ìsáyà sì tún sọ pé:

40 “Ó ti fọ́ wọn lójú,Ó sì ti sé àyà wọn le;Kí wọn má baà fi ojú wọn rí,Kí wọn má ba à fi ọkàn wọn mọ̀,Kí wọn má baà yípadà, kí wọn má baà mú wọn láradá.”

41 Nǹkan wọ̀nyí ni Ìsáyà wí, nítorí ó ti rí ògo rẹ̀, ó sì sọ̀rọ̀ rẹ̀.

42 Síbẹ̀ ọ̀pọ̀ nínú àwọn olórí gbà á gbọ́ pẹ̀lú; ṣùgbọ́n nítorí àwọn Farisí wọn kò jẹ́wọ́ rẹ̀, kí a má ba à yọ wọ́n kúrò nínú Sínágọ́gù:

43 Nítorí wọ́n fẹ́ ìyìn ènìyàn ju ìyìn ti Ọlọ́run lọ.

44 Jésù sì kígbe ó sì wí pé, “Ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, èmi kọ́ ni ó gbàgbọ́ ṣùgbọ́n ẹni tí ó rán mi.

45 Ẹni tí ó bá sì rí mi, ó rí ẹni tí ó rán mi.

46 Èmi ni ìmọ́lẹ̀ tí ó wá sí ayé, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mí gbọ́ má ṣe wà nínú òkùnkùn.

47 “Bí ẹnikẹ́ni bá sì gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí kò sì pa wọ́n mọ́, èmi kì yóò ṣe ìdájọ́ rẹ̀ nítorí tí èmi kò wá láti ṣe ìdájọ́ ayé, bí kò ṣe láti gba ayé là.

48 Ẹni tí ó bá kọ̀ mí, tí kò sì gba ọ̀rọ̀ mi, ó ní ẹnìkan tí ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀; ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ, òun náà ni yóò ṣe ìdájọ́ rẹ̀ ní ọjọ́ ìkẹ́yìn.

49 Nítorí èmi kò dá ọ̀rọ̀ sọ fún ara mi, ṣùgbọ́n Baba tí ó rán mi, òun ni ó ti fún mi ní àṣẹ, ohun tí èmi ó sọ, àti èyí tí èmi ó wí.

50 Èmi sì mọ̀ pé ìyè àìnípẹ̀kun ni òfin rẹ̀: nítorí náà, àwọn ohun tí mo bá wí, gẹ́gẹ́ bí Baba ti sọ fún mi, bẹ́ẹ̀ ni mo wí!”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21