1 Nígbà tí Jésù sì ti sọ nǹkan wọ̀nyí tán, ó jáde pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sókè odò Kédírónì, níbi tí àgbàlá kan wà, nínú èyí tí ó wọ̀, Òun àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.
2 Júdásì, ẹni tí ó dà á, sì mọ ibẹ̀ pẹ̀lú: nítorí nígbà púpọ̀ ni Jésù máa ń lọ síbẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.
3 Nígbà náà ni Júdásì, lẹ́yìn tí ó ti gba ẹgbẹ́ ọmọ ogun, àti àwọn oníṣẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí wá síbẹ̀ ti àwọn ti fìtílà àti ògùṣọ̀, àti ohun ìjà.
4 Nítorí náà bí Jésù ti mọ ohun gbogbo tí ń bọ̀ wá bá òun, ó jáde lọ, ó sì wí fún wọn pé, “Ta ni ẹ ń wá?”
5 Wọ́n sì dá a lóhùn wí pé, “Jésù ti Násárétì.”Jésù sì wí fún wọn pé, “Èmi nìyí.” (Àti Júdásì ọ̀dàlẹ̀, dúró pẹ̀lú wọn.)
6 Nítorí náà bí ó ti wí fún wọn pé, “Èmi nìyí, wọ́n bì sẹ́yìn, wọ́n sì ṣubú lulẹ̀.”
7 Nítorí náà ó tún bi wọ́n léèrè, wí pé, “Ta ni ẹ ń wá?”Wọ́n sì wí pé, “Jésù ti Násárétì.”
8 Jésù dáhùn pé, “Mo ti wí fún yín pé, èmi nìyí: ǹjẹ́ bí èmi ni ẹ bá ń wá, ẹ jẹ́ kí àwọn wọ̀nyí máa lọ:
9 Kí ọ̀rọ̀ nì kí ó lè ṣẹ, èyí tó wí pé, Àwọn tí ìwọ fi fún mi, èmi kò sọ ọ̀kan nù nínú wọn.”
10 Nígbà náà ni Símónì Pétérù ẹni tí ó ní idà, fà á yọ, ó sì sá ọmọ-ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, ó sì ké etí ọ̀tún rẹ̀ sọnù. Orúkọ ìránṣẹ́ náà amá a jẹ́ Mákọ́ọ̀sì.
11 Nítorí náà Jésù wí fún Pétérù pé, “Tẹ idà rẹ bọ inú àkọ̀ rẹ: ago tí baba ti fi fún mi, èmi ó ṣe aláìmu ún bí?”
12 Nígbà náà ni ẹgbẹ́ ọmọ-ogun àti olórí ẹ̀sọ́, àti àwọn oníṣẹ́ àwọn Júù mú Jésù, wọ́n sì dè é.
13 Wọ́n kọ́kọ́ fà á lọ sọ́dọ̀ Ánnà; nítorí òun ni àna Káyáfà, ẹni tí í ṣe olórí àlùfáà ní ọdún náà.
14 Káyáfà sáà ni ẹni tí ó ti bá àwọn Júù gbìmọ̀ pé, ó ṣàǹfàní kí ènìyàn kan kú fún àwọn ènìyàn.
15 Símónì Pétérù sì ń tọ Jésù lẹ́yìn, àti ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn kan: ọmọ-ẹ̀yìn náà jẹ́ ẹni mímọ̀ fún olórí àlùfáà, ó sì bá Jésù wọ ààfin olórí àlùfáà lọ.
16 Ṣùgbọ́n Pétérù dúró ní ẹnu ọ̀nà lóde. Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn náà tí í ṣe ẹni mímọ̀ fún olórí àlùfáà jáde, ó sì bá olùsọ́nà náà sọ̀rọ̀, ó sì mú Pétérù wọlé.
17 Nígbà náà ni ọmọbìnrin náà tí ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà wí fún Pétérù pé, “Ìwọ pẹ̀lú ha ń ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ọkùnrin yìí bí?”Ó wí pé, “Èmi kọ́.”
18 Àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ àti àwọn alaṣẹ́ sì dúró níbẹ̀, àwọn ẹni tí ó ti dáná nítorí òtútù mú, wọ́n sì ń yáná: Pétérù sì dúró pẹ̀lú wọn, ó ń yáná.
19 Nígbà náà ni olórí àlùfáà bi Jésù léèrè ní ti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, àti ní ti ẹ̀kọ́ rẹ̀.
20 Jésù dá a lóhùn pé, “Èmi ti sọ̀rọ̀ ní gbangba fún aráyé; nígbà gbogbo ni èmi ń kọ́ni nínú Sínágọ́gù, àti ní Tẹ́ḿpìlì níbi tí gbogbo àwọn Júù ń pé jọ sí: èmi kò sì sọ ohun kan ní ìkọ̀kọ̀.
21 Èé ṣe tí ìwọ fi ń bi mí léèrè? Béèrè lọ́wọ́ àwọn tí ó ti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, ohun tí mo wí fún wọn: wò ó, àwọn wọ̀nyí mọ ohun tí èmi wí.”
22 Bí ó sì ti wí èyí tan, ọ̀kan nínú àwọn alasẹ́ tí ó dúró tì í fi ọwọ́ rẹ̀ lu Jésù, pé, “Olórí àlùfáà ni ìwọ ń dá lóhùn bẹ́ẹ̀?”
23 Jésù dá a lóhùn pé, “Bí mo bá sọ̀rọ̀ búburú, jẹ́rìí sí búburú náà: ṣùgbọ́n bí rere bá ni, èé ṣe tí ìwọ fi ń lù mí?”
24 Nítorí Ánnà rán an lọ ní dídè sọ́dọ̀ Káyáfà olórí àlùfáà.
25 Ṣùgbọ́n Símónì Pétérù dúró, ó sì ń yáná. Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “Ìwọ pẹ̀lú ha jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀?”Ó sì ṣẹ́, wí pé, “Èmi kọ́.”
26 Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, tí ó jẹ́ ìbátan ẹni tí Pétérù gé etí rẹ̀ sọnù, wí pé, “Èmi ko ha rí ọ pẹ̀lú rẹ̀ ní àgbàlá?”
27 Pétérù tún ṣẹ́: lójú kan náà àkùkọ sì kọ.
28 Nígbà náà, wọ́n fa Jésù láti ọ̀dọ̀ Káyáfà lọ sí ibi gbọ̀ngàn ìdájọ́: ó sì jẹ́ kùtùkùtù òwúrọ̀; àwọn tìkara wọn kò wọ inú gbọ̀ngàn ìdájọ́, kí wọn má ṣe di aláìmọ́, ṣùgbọ́n kí wọn lè jẹ àsè ìrékọjá.
29 Nítorí náà Pílátù jáde tọ̀ wọ́n lọ, ó sì wí pé, “Ẹ̀sùn kín ní ẹ̀yin mú wá sí ọkùnrin yìí?”
30 Wọ́n sì dáhùn wí fún un pé, “Ìbá má ṣe pé ọkùnrin yìí ń hùwà ibi, a kì bá tí fà á lé ọ lọ́wọ́.”
31 Nítorí náà Pílátù wí fún wọn pé, “Ẹ mú un tìkára yín, kí ẹ sì ṣe ìdájọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òfin yín.”Nítorí náà ni àwọn Júù wí fún un pé, “Kò tọ́ fún wa láti pa ẹnikẹ́ni.”
32 Kí ọ̀rọ̀ Jésù ba à lè ṣẹ, èyí tí ó sọ tí ó ń ṣàpẹẹrẹ irú ikú tí òun yóò kú.
33 Nítorí náà Pílátù tún wọ inú gbọ̀ngàn, ìdájọ́ lọ, ó sì pe Jésù, ó sì wí fún un pé, “Ìwọ há ni a ni Ọba àwọn Júù bí?”
34 Jésù dáhùn pé, “Èrò ti ara rẹ ni èyí, tàbí àwọn ẹlòmíràn sọ ọ́ fún ọ nítorí mi?”
35 Pílátù dáhùn wí pé, “Èmi ha jẹ́ Júù bí? Àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè rẹ, àti àwọn olórí àlùfáà ni ó fà ọ́ lé èmi lọ́wọ́: kín ní ìwọ ṣe?”
36 Jésù dáhùn wí pé, “Ìjọba mi kì í ṣe ti ayé yìí: ìbáṣe pé ìjọba mi jẹ́ ti ayé yìí, àwọn ìránṣẹ́ mi ìbá jà, kí a má baà fi mí lé àwọn Júù lọ́wọ́: ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìjọba mi kì í ṣe láti ìhín lọ.”
37 Nítorí náà Pílátù wí fún un pé, “Ọba ni ó nígbà náà?”Jésù dáhùn wí pé, “Ìwọ wí pé, Ọba ni èmi jẹ́. Nítorí èyí ni a ṣe bí mí, àti nítorí ìdí èyí ni mo sì ṣe wá kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́, olúkúlùkù ẹni tí í ṣe ti òtítọ́ ń gbọ́ ohùn mi.”
38 Pílátù wí fún un pé, “Kín ni òtítọ́?” Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó tún jáde tọ àwọn Júù lọ, ó sì wí fún wọn pé, “Èmi kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́wọ́ rẹ̀.
39 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ní àṣà kan pé, kí èmi dá ọ̀kan sílẹ̀ fún yín nígbà àjọ ìrékọjá: nítorí náà ẹ ó ha fẹ́ kí èmi dá Ọba àwọn Júù sílẹ̀ fún yín bí?”
40 Nítorí náà gbogbo wọn tún kígbe pé, “Kì í ṣe ọkùnrin yìí, bí kò ṣe Bárábà!” Ọlọ́sà sì ni Bárábà.