20 Nítorí náà, nígbà tí Màta gbọ́ pé Jésù ń bọ̀ wá, ó jáde lọ pàdé rẹ̀: ṣùgbọ́n Màríà jòkó nínú ilé.
21 Nígbà náà, ni Màta wí fún Jésù pé, “Olúwa, ìbá ṣe pé ìwọ ti wà níhìn-ín, arákùnrin mi kì bá kú.
22 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí náà, mo mọ̀ pé, ohunkóhun tí ìwọ bá bèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, Ọlọ́run yóò fi fún ọ.”
23 Jésù wí fún un pé, “Arákùnrin rẹ yóò jíǹde.”
24 Màta wí fún un pé, “Mo mọ̀ pé yóò jíǹde ní àjíǹde ìkẹyìn.”
25 Jésù wí fún un pé, “Èmi ni àjíǹde àti ìyè: ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, bí ó tilẹ̀ kú, yóò yè:
26 Ẹnikẹ́ni tí ó ń bẹ láàyè, tí ó sì gbà mí gbọ́, kì yóò kú láéláé ìwọ gbà èyí gbọ́?”