26 Ẹnikẹ́ni tí ó ń bẹ láàyè, tí ó sì gbà mí gbọ́, kì yóò kú láéláé ìwọ gbà èyí gbọ́?”
27 Ó wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa: èmi gbàgbọ́ pé, ìwọ ni Kírísítì náà Ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí ń bọ̀ wá sí ayé.”
28 Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó lọ, ó sì pe Màríà arábìnrin rẹ̀ sẹ́yìn wí pé, “Olùkọ́ dé, ó sì ń pè ọ́.”
29 Nígbà tí ó gbọ́, ó dìde lọ́gán, ó sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀.
30 Jésù kò tíì wọ ìlú, ṣùgbọ́n ó wà ní ibi kan náà tí Màrta ti pàdé rẹ̀.
31 Nígbà tí àwọn Júù tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nínú ilé, tí wọ́n ń tù ú nínú rí Màríà tí ó dìde kánkán, tí ó sì jáde, wọ́n tẹ̀lé, wọ́n ṣebí ó ń lọ sí ibojì láti sọkún níbẹ̀.
32 Nígbà tí Màríà sì dé ibi tí Jésù wà, tí ó sì rí i, ó wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó wí fún un pé, “Olúwa, ìbáṣe pé ìwọ ti wà níhín-ín, arákùnrin mi kì bá kú.”