41 Nígbà náà ni wọ́n gbé òkúta náà kúrò (níbi tí a tẹ́ ẹ sí). Jésù sì gbé ojú rẹ̀ sókè, ó sì wí pé, “Baba, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ nítorí tí ìwọ gbọ́ tèmi.
42 Èmi sì ti mọ̀ pé, ìwọ a máa gbọ́ ti èmi nígbà gbogbo: ṣùgbọ́n nítorí ìjọ ènìyàn tí ó dúró yìí ni mo ṣe wí i, kí wọn baà lè gbàgbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi.”
43 Nígbà tí ó sì wí bẹ́ẹ̀ tan, ó kígbe lóhùn rara pé, “Lásárù, jáde wá.”
44 Ẹni tí ó kú náà sì jáde wá, tí a fi aṣọ òkú dì tọwọ́ tẹsẹ̀ a sì fi gèlè dì í lójú.Jésù wí fún wọn pé, “Ẹ tú u, ẹ sì jẹ́ kí ó má a lọ!”
45 Nítorí náà ni ọ̀pọ̀ àwọn Júù tí ó wá sọ́dọ̀ Màríà, tí wọ́n rí ohun tí Jésù ṣe, ṣe gbà á gbọ́.
46 Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn nínú wọn tọ àwọn Farisí lọ, wọ́n sì sọ fún wọn ohun tí Jésù ṣe.
47 Nígbà náà ni àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí pe ìgbìmọ̀ jọ, wọ́n sì wí pé,“Kínni àwa ń ṣe? Nítorí ọkùnrin yìí ń ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àmì.