14 Ọ̀rẹ́ mi ni ẹ̀yin ń ṣe, bí ẹ bá ṣe ohun tí èmi pàṣẹ fún yín.
15 Èmi kò pè yín ní ọmọ ọ̀dọ̀ mọ́; nítorí ọmọ ọ̀dọ̀ kò mọ ohun tí olúwa rẹ̀ ń ṣe: ṣùgbọ́n èmi pè yín ní ọ̀rẹ́ nítorí ohun gbogbo tí mo ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Baba mi wá, mo ti fi hàn fún yín.
16 Kì í ṣe ẹ̀yin ni ó yàn mí, ṣùgbọ́n èmi ni ó yàn yín, mo sì fi yín sípò, kí ẹ̀yin kí ó lè lọ, kí ẹ sì so èso, àti kí èṣo yín lè dúró; kí ohunkóhun tí ẹ bá bèrè lọ́wọ́ Baba ní orúkọ mi, kí ó lè fi í fún yín.
17 Nǹkan wọ̀nyí ni mo paláṣẹ fún yín pé, kí ẹ̀yin kí ó fẹ́ràn ara yín.
18 “Bí ayé bá kóríra yín, ẹ mọ̀ pé, ó ti kóríra mi ṣáájú yín.
19 Ìbáṣepé ẹ̀yin ń ṣe ti ayé, ayé ìbá fẹ́ àwọn tirẹ̀; ṣùgbọ́n nítorí tí ẹ̀yin kì ń ṣe ti ayé, ṣùgbọ́n èmi ti yàn yín kúrò nínú ayé, nítorí èyí ni ayé ṣe kórìíra yín.
20 Ẹ rántí ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fún yín pé, ‘Ọmọ ọ̀dọ̀ kò tóbi ju olúwa rẹ̀ lọ.’ Bí wọ́n bá ti ṣe inúnibíni sí mi, wọ́n ó ṣe inúnibíni sí yín pẹ̀lú: bí wọ́n bá ti pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, wọ́n ó sì pa ti yín mọ́ pẹ̀lú.