21 Nígbà tí obìnrin bá ń rọbí, a ní ìbìnújẹ́, nítorí tí wákàtí rẹ̀ dé: ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá ti rí ọmọ náà tán, òun kì í sì í rántí ìrora náà mọ́, fún ayọ̀ nítorí a bí ènìyàn sí ayé.
22 Nítorí náà ẹ̀yin ní ìbànújẹ́ nísinsìn yìí: ṣùgbọ́n èmi ó tún rí yín, ọkàn yín yóò sì yọ̀, kò sì sí ẹni tí yóò gba ayọ̀ yín lọ́wọ́ yín.
23 Àti ní ijọ́ náà ẹ̀yin kì ó bi mí lérè ohunkóhun. Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ohunkóhun tí ẹ̀yin bá bèèrè lọ́wọ́ Baba ní orúkọ mi, òhun ó fi fún yín.
24 Títí di ìsinyìí ẹ kò tíì bèèrè ohunkóhun ní orúkọ mi: ẹ bèèrè, ẹ ó sì rí gbà, kí ayọ̀ yín kí ó lè kún.
25 “Nǹkan wọ̀nyí ni mo fi òwe sọ fún yín: ṣùgbọ́n àkókò dé, nígbà tí èmi kì yóò fi òwe bá yín sọ̀rọ̀ mọ́, ṣùgbọ́n èmi ó sọ ti Baba fún yín gbangba.
26 Ní ọjọ́ náà, ẹ̀yin ó béèrè ní orúkọ mi: èmi kò sì wí fún yín pé, èmi ó bèèrè lọ́wọ́ Baba fún yín:
27 Nítorí tí Baba tìkara rẹ̀ fẹ́ràn yín, nítorí tí ẹ̀yin ti fẹ́ràn mi, ẹ sì ti gbàgbọ́ pé, lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni èmi ti jáde wá.