1 Ní ọjọ́ kẹ́ta, a ń ṣe ìgbéyàwó kan ní Kánà ti Gálílì. Ìyá Jésù sì wà níbẹ̀,
2 A sì pe Jésù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sí ibi ìgbéyàwó náà.
3 Nígbà tí wáìnì sì tán, ìyá Jésù wí fún un pé, “Wọn kò ní wáìnì mọ́.”
4 Jésù fèsì pé, “Arábìnrin ọ̀wọ́n, èése tí ọ̀rọ̀ yìí fi kàn mí? Àkókò mi kò tí ì dé.”
5 Ìyá rẹ̀ wí fún àwọn ìránṣẹ́ náà pé, “Ẹ ṣe ohunkóhun tí ó bá wí fún yín.”
6 Ìkòkò òkúta omi mẹ́fà ni a sì gbé kalẹ̀ níbẹ̀, irú èyí tí àwọn Júù máa ń fi ṣe ìwẹ̀nù, èyí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn gbà tó ìwọ̀n ogún sí ogójì gálọ́ọ̀nù.
7 Jésù wí fún àwọn ìránṣẹ́ náà pé, “Ẹ pọn omi kún ìkòkò wọ̀nyí.” Wọ́n sì pọn omi kún wọn títí dé etí.