1 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jésù tún fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ létí òkun Tíbéríà; báyìí ni ó sì farahàn.
2 Símónì Pétérù, àti Tọ́másì tí a ń pè ní Dídímù, àti Nátanáẹ́lì ará Kánà ti Gálílì, àti àwọn ọmọ Sébédè, àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjì mìíràn jùmọ̀ wà pọ̀.
3 Símónì Pétérù wí fún wọn pé, “Èmi ń lọ pẹja!” Wọ́n wí fún un pé, “Àwa pẹ̀lú ń bá ọ lọ.” Wọ́n jáde, wọ́n sì wọ inú ọkọ̀ ojú omi; ní òru náà wọn kò sì mú ohunkóhun.
4 Ṣùgbọ́n nígbà tí ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí mọ́, Jésù dúró létí òkun: ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kò mọ̀ pé Jésù ni.
5 Jésù wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ọmọdé, ẹ ní oúnjẹ díẹ̀ bí?”Wọ́n dá a lóhùn pé, “Rárá o.”
6 Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ sọ àwọ̀n sí apá ọ̀tún ọkọ̀ ojú omi, ẹ̀yin ó sì rí.” Nígbà tí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, wọn kò sì lè fà á jáde nítorí ọ̀pọ̀ ẹja.