Jòhánù 21:15-21 BMY

15 Ǹjẹ́ lẹ́yìn, ìgbà tí wọ́n jẹun òwúrọ̀ tan, Jésù wí fún Símónì Pétérù pé, “Símónì, ọmọ Jónà, ìwọ fẹ́ mi ju àwọn wọ̀nyí lọ bí?”Ó sì wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa; ìwọ mọ̀ pé, mo fẹ́ràn rẹ.”Ó wí fún un pé, “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi.”

16 Ó tún wí fún un nígbà kejì pé, “Símónì ọmọ Jónà, ìwọ fẹ́ mi bí?”Ó wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa; ìwọ mọ̀ pé, mo fẹ́ràn rẹ.”Ó wí fún un pé, “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi.”

17 Ó wí fún un nígbà kẹ́ta pé, “Símónì, ọmọ Jónà, ìwọ fẹ́ràn mi bí?”Inú Pétérù sì bàjẹ́, nítorí tí ó wí fún un nígbà ẹ̀kẹ́ta pé, “Ìwọ fẹ́ràn mi bí?” Ó sì wí fún un pé, “Olúwa, ìwọ mọ ohun gbogbo; ìwọ mọ̀ pé, mo fẹ́ràn rẹ.”Jésù wí fún un pé, “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi.”

18 Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, nígbà tí ìwọ wà ní ọ̀dọ́mọdé, ìwọ a máa di ara rẹ ní àmùrè, ìwọ a sì máa rìn lọ sí ibi tí ìwọ bá fẹ́: ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá di arúgbó, ìwọ ó na ọwọ́ rẹ jáde, ẹlòmíràn yóò sì dì ọ́ ní àmùrè, yóò mú ọ lọ sí ibi tí ìwọ kò fẹ́.

19 (Ó wí èyí, ó fi ń ṣàpẹrẹ irú ikú tí yóò fi yin Ọlọ́run lógo.) Lẹ́yìn ìgbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó wí fún un pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”

20 Pétérù sì yípadà, ó rí ọmọ-ẹ̀yìn náà, ẹni tí Jésù fẹ́ràn, ń bọ̀ lẹ́yìn; ẹni tí ó fararọ̀ súnmọ́ àyà rẹ̀ nígbà oúnjẹ alẹ́ tí ó sì wí fún un pé, “Olúwa, ta ni ẹ̀ni tí ó fi ọ́ hàn?”

21 Nígbà tí Pétérù rí i, ó wí fún Jésù pé, “Olúwa, Eléyìí ha ńkọ́?”