5 Jésù wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ọmọdé, ẹ ní oúnjẹ díẹ̀ bí?”Wọ́n dá a lóhùn pé, “Rárá o.”
6 Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ sọ àwọ̀n sí apá ọ̀tún ọkọ̀ ojú omi, ẹ̀yin ó sì rí.” Nígbà tí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, wọn kò sì lè fà á jáde nítorí ọ̀pọ̀ ẹja.
7 Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn náà tí Jésù fẹ́ràn wí fún Pétérù pé, “Olúwa ni!” Nígbà tí Símónì Pétérù gbọ́ pé Olúwa ni, bẹ́ẹ̀ ni ó di àmùrè ẹ̀wù rẹ̀ mọ́ra, nítorí tí ó wà ní ìhòòhò, ó sì gbé ara rẹ̀ sọ sínú òkun.
8 Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ìyókù mú ọkọ̀ ojú omi kékeré kan wá nítorí tí wọn kò jìnà sílẹ̀, ṣùgbọ́n bí ìwọ̀n igba ìgbọ̀nwọ́; wọ́n ń wọ́ àwọ̀n náà tí ó kún fún ẹja.
9 Nígbà tí wọ́n gúnlẹ̀, wọ́n rí ẹ̀yinná níbẹ̀ àti ẹja lórí rẹ̀ àti àkàrà.
10 Jésù wí fún wọn pé, “Ẹ mú nínú ẹja tí ẹ pa nísinsin yìí wá.”
11 Nítorí náà Símónì Pétérù gòkè, ó sì fa àwọ̀n náà wálẹ̀, ó kún fún ẹja ńlá, ó jẹ́ mẹ́taléláádọ́jọ: bí wọ́n sì ti pọ̀ tó náà, àwọ̀n náà kò ya.