10 Jésù dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Ìbáṣepé ìwọ mọ ẹ̀bùn Ọlọ́run, ati ẹni tí ó wí fún ọ pé, fún mi mu, ìwọ ìbá sì ti bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀, Òun ìbá ti fi omi ìyè fún ọ.”
11 Obìnrin náà wí fún un pé, “Alàgbà, ìwọ kò ní nǹkan tí ìwọ ó fi fà omi, bẹ́ẹ̀ ni kànga náà jìn: Níbo ni ìwọ ó ti rí omi ìyè náà?
12 Ìwọ pọ̀ ju Jákọ́bù baba wa lọ bí, ẹni tí ó fún wa ní kànga náà, tí Òun tìkararẹ̀ mu nínú rẹ̀, àti àwọn ọmọ rẹ̀, àti àwọn ẹran rẹ̀?”
13 Jésù dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá mu nínú omi yìí, òrùngbẹ yóò tún gbẹ ẹ́:
14 Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá mu nínú omi tí èmi ó fí fún un, òrùngbẹ kì yóò gbẹ ẹ́ mọ́ láé; ṣùgbọ́n omi tí èmi ó fi fún un yóò di kànga omi nínú rẹ̀, tí yóò máa sun títí ayérayé.”
15 Obìnrin náà sì wí fún u pé, “Alàgbà, fún mi ní omi yìí, kí òùngbẹ kí ó má se gbẹ mí, kí èmi kí ó má sì wá máa pọn omi níbí.”
16 Jésù wí fún un pé, “Lọ pe ọkọ rẹ, kí ó sì padà wá sí ìhín yìí.”