29 Wọn ó sì jáde wá; àwọn tí ó ṣe rere, sí àjíǹde ìyè; àwọn tí ó sì ṣe búburú sí àjíǹde ìdájọ́.
30 “Èmi kò le ṣe ohun kan fún ara mi: bí mo ti ń gbọ́, mo ń dájọ́: òdodo sì ni ìdájọ́ mi; nítorí èmi kò wá ìfẹ́ ti èmi fúnra mi, bí kò se ìfẹ́ ti ẹni tí ó rán mi.
31 “Bí èmi bá ń jẹ́rìí ara mi, ẹ̀rí mi kì í ṣe òtítọ́.
32 Ẹlòmíràn ni ẹni tí ń jẹ́rìí mi; èmi sì mọ̀ pé, òtítọ́ ni ẹrí mi tí ó jẹ́.
33 “Ẹ̀yin ti ránsẹ́ lọ sọ́dọ̀ Jòhánù, òun sì ti jẹ́rìí sí òtítọ́.
34 Ṣùgbọ́n èmi kò gba jẹ̀rìí lọ́dọ̀ ènìyàn: nǹkan wọ̀nyí ni èmi ń sọ, kí ẹ̀yin lè là.
35 Òun ni fìtílà tí ó ń jó, tí ó sì ń tànmọ́lẹ̀: ẹ̀yin sì fẹ́ fún sáà kan láti máa yọ̀ nínú ìmọ́lẹ̀ rẹ̀.