1 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jésù kọjá sí apákejì òkun Gálílì, tí í ṣe òkun Tiberíà.
2 Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, nítorí tí wọ́n rí iṣẹ́ àmì rẹ̀ tí ó ń ṣe lára àwọn aláìsàn.
3 Jésù sì gun orí òkè lọ, níbẹ̀ ni ó sì gbé jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yin rẹ̀.
4 Àjọ ìrékọjá ọdún àwọn Júù sì sún mọ́ etílé.
5 Ǹjẹ́ bí Jésù ti gbé ojú rẹ̀ sókè, tí ó sì rí ọ̀pọ̀ ènìyàn wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó wí fún Fílípì pé, “Níbo ni a ó ti ra àkàrà, kí àwọn wọ̀nyí lè jẹ?”