21 Nítorí náà wọ́n fi ayọ̀ gbà á sínú ọkọ̀; lójúkannáà ọkọ̀ náà sì dé ilẹ̀ ibi tí wọ́n gbé ń lọ.
22 Ní ijọ́ kéjì nígbà tí àwọn ènìyàn tí ó dúró ní apákejì òkun ríi pé, kò sí ọkọ̀ ojú omi mìíràn níbẹ̀, bí kò ṣe ọ̀kan náà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ̀, àti pé Jésù kò bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ inú ọkọ̀ ojú omi náà, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ nìkan ni ó lọ.
23 Ṣùgbọ́n àwọn ọkọ̀ ojú omi mìíràn ti Tiberíà wá, létí ibi tí wọn gbé jẹ àkàrà, lẹ́yìn ìgbà tí Olúwa ti dúpẹ́;
24 Nítorí náà nígbà tí àwọn ènìyàn rí i pé Jésù tàbí ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kò sí níbẹ̀, àwọn pẹ̀lú wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí Kápánámù, wọ́n ń wá Jésù.
25 Nígbà tí wọ́n sì rí i ní apákejì òkun, wọ́n wí fún un pé, “Rábì, nígbà wo ni ìwọ wá síhín yìí?”
26 Jésù dá wọn lóhùn ó sì wí pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún yín. Ẹ̀yin ń wá mi, kì í ṣe nítorí tí ẹ̀yin rí iṣẹ́-àmì, ṣùgbọ́n nítorí ẹ̀yin jẹ àjẹyó ìṣù àkàrà.
27 Ẹ má ṣe ṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tí ńṣègbé, ṣùgbọ́n fún oúnjẹ tí ó wà títí di ìyè àìnípẹ̀kun, èyí tí ọmọ-ènìyàn yóò fi fún yín: nítorí pé òun ni, àní Ọlọ́run Baba ti fi èdìdì dì í.”