67 Nítorí náà Jésù wí fún àwọn méjìlá pé, “Ẹ̀yin pẹ̀lú ń fẹ́ lọ bí?”
68 Nígbà náà ni Símónì Pétérù dá a lóhùn pé, “Olúwa, ọ̀dọ̀ ta ni àwa ó lọ? Ìwọ ni ó ni ọ̀rọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun.
69 Àwa sì ti gbàgbọ́, a sì mọ̀ pé ìwọ ni Kristì náà, Ọmọ Ọlọ́run alààyè.”
70 Jésù dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin méjìlá kọ́ ni mo yàn, ọ̀kan nínú yín kò ha sì ya Èṣù?”
71 (Ó ń sọ ti Júdásì Iskariótù Ọmọ Símónì ọ̀kan nínú àwọn méjìlá: nítorí pé òun ni ẹni tí yóò fi í hàn.)